Ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun,G A Ọtunla ti mu da awọn eeyan loju pe ọrọ aje yoo tubọ tẹsiwaju lẹnu bode Idi iroko nipinlẹ Ogun, eyi ti yoo tubọ mu ki nnkan ko maa gun rege si.
O sọrọ ọhun lakooko to n gba awọn olokoowo alabaṣiṣẹ pọ lalejo ni Idi Iroko, nibi ti wọn ti jọ ṣapero lori bi ajọṣepọ to danmọran yoo ṣe wa lawọn ẹnu bode nipinlẹ Ogun pẹlu awọn to mule ti wọn.
Nibẹ ni wọn ti jọ jiroro nipa bi ohun gbogbo yoo ṣe di irọrun. Awọn aṣoju lati orileede Benin naa wa nibi ipade yi.
Ọtunla ṣalaye siwaju pe pataki ni eto aabo jẹ, idi si niyii tawọn ko ṣe le fọwọ rọ sẹyin nibi ijiroro wọn ti wọn si fẹnu ko lori bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ pọ le lori tawọn orileede mejeeji yoo si maa ṣiṣẹ wọn pẹlu ifọkanbalẹ.
Atẹjade ipade ọhun eyi ti agbẹnusọ awọn aṣọbode nipinlẹ Ogun, Chado Zakari, fi sita tun ṣalaye pe dandan ni eto ọrọ aje lorileede yii ati ti Benin to mule ti wọn, idi si niyi tawọn fi gbọdọ maa forikori lati maa wa ọna abayp sawọn ohun to ba fẹẹ jẹ ipenija.
Ọtunla waa dupẹ lọwọ awọn ọmọọṣẹ lori ifarajin ti wọn ni lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo ọhun bẹẹ lo tun fẹmi imoore han si ọga wọn pata lorileede yii, Bahir Adewale Adeniyi fawọn atilẹyin ti wọn ri gba loorekoore.
No comments:
Post a Comment