Laipẹ ni okiki ẹgbẹ oṣere tiata IMMAN yoo tun gba igboro-Gomina ẹgbẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 6 May 2025

Laipẹ ni okiki ẹgbẹ oṣere tiata IMMAN yoo tun gba igboro-Gomina ẹgbẹ


Laipẹ ni okiki ẹgbẹ oṣere tiata IMMAN yoo tun gba igboro-Gomina ẹgbẹ

Gomina fẹgbẹ oṣere tiata IMMAN nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Ọlayẹmi Olowu ti miu da gbogbo ẹgbẹ loju pe laipẹ yii n ogo ẹgbẹ naa yoo tun pada bọ sipo, ti okiki yoo tun maa tan kaakiri agbaye.

Ọkunrin naa sọrọ yiii nibi ipade ẹgbẹ wọn to waye niluu Abẹokuta, o sọ pe agbo wọn to tadi mẹyin agbara lo lọ mu wa ati pe awọn ti ṣetan lati gbe ẹgbẹ ọhun dide pada.

O ṣọ pe ọpọ ipenija lawọn n koju lori ẹgbẹ oṣere yio amọ idaniloju wa pe gbogbo ẹ ti n dopin, tawọn si ti bẹrẹ lati maa wọ lokeṣan yii.

Gomina wa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ ọmọ ẹgbẹ nitori agbajọ ọwọ la fi sọya pẹlu adura pe gbogbo wọn ni wọn yoo fiṣẹ ọhun di ẹni giga.

Nibi ipade ọhun ni wọn ti yan awọn ti yoo  maa ṣe adari ere pẹlu ileri pe gbogbo wọn yoo jọ maa ṣiṣẹ pọ bo mọlẹbi kan ṣoṣo.

Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni Oloye Folusho Alao, igbakeji Gomina, Oluwapelumi Akindele, akọwe4. ⁠ Sulaimon Omotosho, Ajosẹ, Alaba Philips, Adeniyi Olubunmi, Olaolu, Joseph Segun, Obayemi, Biobaku Emmanuel


No comments:

Post a Comment

Pages