Ọmọọba Babajide Adefowora, ẹni tawọn araalu Ketu Ẹpẹ fa kalẹ gẹgẹ bi ọba wọn ti sọ pe irinajo oun sọdọ Ọọni tile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi, ki i ṣe fun faaji bi ko ṣe lati jẹ ko mọ bi nnkan ṣe n lọ si ati bi wọn ṣe fa oun kalẹ fun ipo ọba.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ,o sọ pe ọrọ ti Akimu Oluwo to ba o dupo ọba sọ pe faaji lasan loun lọ ṣe jinna si ootọ ati pe simọkan lo n da laamu.
O sọ pe Baba oun ni Ọọni, oun si lọ lati jẹ ki wọn mọ pe oun ni wọn fa kalẹ gẹgẹ bi Alaketu Ẹpẹ.
O tẹsiwaju pe inu Kabiyesi dun lati gba wọn lalejo, to si wure foun pẹlu, koda tẹrin tọyaya ni wọn fi gba oun atawọn araalu lalejo.
Ọmọọba Babajide tun tẹsiwaju pe irọ pata gba a ni Akimu pa pe ẹbi kan naa lawọn ati pe ipo ọba naa tọ si oun.
O ṣalaye lati ibẹrẹ pẹpẹ ni wọn ti mọ pe idile Ọṣọkeji Atẹṣinmara nikan lo n jọba ati pe awọn ko gbọ ninu itan pe idile Adeọna jọba niluu Ketu Ẹpẹ ri.
O fikun ọrọ ẹ pe oye Oluwo ni idile Akimu n jẹ niluu naa ṣugbọn bo ṣe fẹẹ wa sọ ara ẹ di ọba ti wọn ki i jẹ ninu iran wọn lo ya oun lẹnu.
O waa sọ pe ki i ṣe pe oun ati Akimu Oluwo n ja o, o ni ko si ija kankan laarin wọn ṣugbọn nnkan tawọn fẹẹ ni ki alaafia jọba.
O waa rọ ijọba ipinlẹ Eko ati ileeṣẹ eto idaji pe ki wọn jẹ ki idajọ ododo waye ati pe ki wọn tẹle idajọ tile ẹjọ giga ju to ti kọkọ waye nibi ti wọn ti fidi ẹ mulẹ Ọṣọkeji Atẹṣimara nikan lo lẹtọọ sipo ọba ilu naa
Bẹẹ lo pari ọrọ ẹ pe oun fẹẹ ki oun ati Akimu jọ jade sigbooro ilu Ketu Ẹpẹ, kawọn mọ ẹni to ni ero lẹyin ju.
No comments:
Post a Comment