Ọga agba aṣọbode tuntun to ṣẹṣẹ gbaṣẹ nipinlẹ Ogun, Godwin Ọtunla ti ṣeleri pe atunṣe yoo deba gbigbogun tawọn onifayawọ lawọn ẹnu-bode ipinlẹ Ogun ati pe adinku yoo de bawọn laipẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n tẹwọgba iṣẹ lọwọ ẹni to ti wa nibẹ, iyẹn Mohammadu Shuaib. o sọ pe nigba toun si fi n jẹ adari, oun ko nii gba kawọn kan ba tẹ oju ọrọ aje wa mọlẹ ati pe gbogbo ọna lawọn yoo fi ko awọn oṣiṣẹ wọn lọọ sibi tawọn ọbayejẹ fayawọ ba wa.
Ọtunla tun fikun ninu ọrọ ẹ pe oun dupẹ lọwọ ọga agba pata fawọn aṣọbode, Bashir Adeniyi atawọn alaṣẹ yooku fun igbagbọ ti wọn ni si oun pẹlu ileri pe oun yoo rii pe oun ṣiṣẹ ti wọn gbe le oun lọwọ lọna tootọ ati eyi to yẹ.
Bẹẹ lo tun gboriyin fun Mohammmad Shuaib, ẹni to ti wa nibẹ tẹlẹ fawọn ipilẹ rere to ti la silẹ lati tẹle lakooko to wa nibẹ.
O waa sọ pe erongba oun gẹgẹ bi ọga agba tuntun ni lati le ri pe idagbasoke nla tubọ wa fun ipawowọle ọrọ aje ati lati jẹ ki irẹpọ tubọ wa laarin awọn araalu atawọn oṣiṣẹ aṣọbode.
Ko to to akoko naa ni Shuaib to gbe akoso le Ọtunla lọwọ ti mẹnuba awọn aṣeyọri nla to ti ṣe ati bi wọn ṣe pawo wọle laarin oṣu kin in ni si kẹrin ọdun yii.
Bakan naa loun naa dupẹ lọwọ ọga agba wọn pata fun anfaani to fun oun lati jẹ adari nipinlẹ Ogun bẹẹ lo tun fi ẹmi imoore ẹ han si awọn ọmọlẹyin ẹ fun ifọwọsowọpọ wọn.
O waa rọ wọn lati jẹ ki iru nnkan bẹẹ tẹsiwaju pẹlu ọga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa ọhun
No comments:
Post a Comment