Ọga agba fun ẹṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Mohammed Shuaib, ti mu dawọn eeyan ẹ loju pe gbogbo awọn ipenija ti wọn dojukọ nidii iṣẹ ọhun ni yoo di ohun itan laipẹ yii.
Ọkunrin yii naa sọrọ ọhun nibi ayẹyẹ ayajọ fawọn oṣiṣẹ aṣọbode lagbaaye, eyi to waye ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idiroko, nipinlẹ Ogun.
O sọ pe laipẹ yii ni ẹrọ ti wọn fi ṣayẹwo awọn ẹru ti wọn ba ko wọle, ati eyi to jade lorileede wa Naijiria, to wa ni Idiroko bẹrẹ iṣẹ pada.
Shuiab fi kun ọrọ ẹ pe idi ti ẹrọ naa ko ṣe ṣiṣẹ mọ ni pe ọpọ awon ti wọn mọ bi won ṣe n lo maṣiini ọhun ni wọn ti fẹyinti lẹnu iṣẹ, bẹẹ lo ni iṣẹ ti gbe ọpọ wọn kuro nipinlẹ Ogun.
O tẹ siwaju oun ko nii rẹwẹsi ọkan lati maa foju awọn onifayawọ ri mabo, ti wọn ba kọ lati jawọ.
Nigba toun naa sọrọ nibi ayẹyẹ naa,Clement Amawah, igbakeji ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun, sọ pe awọn ti n gbe igbese lati ma sise asobode lọna ti yoo ba igbalode mu.
Ati pe bi wọn yoo ṣe maa pawo wọle ni irọrun sii. Lara igbesẹ ti wọn gbe ni lati ṣeto ẹka kan to n jẹ -‘Customs, single window platform’ ati bẹẹbẹẹ lọ.
O ṣalaye pe awọn ẹka yii ma jẹ ko tun bọ rọrun fawọn oniṣowo lati ṣe gbogbo iwe wọn ki wọn si san awọn owo to ba yẹ sapo ijọba lai mu idaamu kankan lọwọ.
Ọgbẹni Borny to jẹ aṣoju orileede olominira Benin dupẹ lọwọ awọn kọsitọọmu fun akitiyan wọn lati rii pe irẹpọ wa laarin orileede Naijiria ati ilẹ Benin.
O wa rọ ọga agba ajọ ẹsọ asọbode lorile ede Naijiria , Kontirola Adeniyi Adewale lati ṣe gbogbo nnkan to yẹ ko ṣe ki eto ọrọ aje laarin orile ede mejeeji tunbọ gun rege.
No comments:
Post a Comment