Àádọ̀rún wàhálà ajagungbalẹ́ là á n koju nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ògún Ẹlẹ́mídé
Olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun,Oludaisi Oluṣẹgun Ẹlẹmide, ti sọ pe o kere tan iwe ẹsun awọn ajagungbalẹ lawọn ti gba lati bi ọdun kan sẹyin to ti dori ipo naa.
O sọrọ yii lakooko to n sọ nipa aṣeyọri ẹ lati bi ọdun kan to di olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, eyi to waye niluu Abẹokuta lonii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni aba mọkanla lawọn ti gba wọle bẹẹ lo ni mejilelogoji atunṣe to nii ṣe pẹlu alaafia, igbega ati iṣelọba rere lawọn tun ti fọwọ si.
O salaye siwaju pe lori wahala awọn ajagungbalẹ lawọn ti ṣiṣẹ le lori to si ti wa niwaju ati pe eyi to ṣe pataki ninu ẹ ni pe ki awọn ileeṣẹ eto aabo lo gbogbo agbara lati ma foju awọn ajagungbalẹ naa winna ofin.
Ẹlẹmide tun fikun ninu ọrọ ẹ pe ajọṣepọ to danmọran lo wa laarin awọn aṣofin atawọn to n ṣejọba,eyi lo ni o jẹ ki idagbssoke fi n ba ipinlẹ Ogun.
Bẹẹ lo tun lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ awọn aṣofin akẹgbẹ ẹ lori bi wọn ṣe fọwọsowọpọ pẹlu oun lati nnkan bii ọdun kan sẹyin.
O waa sọ pe olori ile igbimọ aṣofin tẹlẹ ti pada si ijokoo bayii lẹyin tile ẹjọ to gbe wọn lọ ti da ẹjọ ẹ nu.
No comments:
Post a Comment