Ṣẹgun Ṣowumi sọ pe: Idaamu nla ni ipinsipo ẹlẹyamẹya maa n ko ba orileede, bẹẹ emi nipo alaga fẹgbẹ PDP lapapọ tọ si. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 30 December 2024

Ṣẹgun Ṣowumi sọ pe: Idaamu nla ni ipinsipo ẹlẹyamẹya maa n ko ba orileede, bẹẹ emi nipo alaga fẹgbẹ PDP lapapọ tọ si.




Ọkan lara agba ẹgbẹ oṣelu PDP lorileede yii, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, ti sọ pe bi wọn ba fẹẹ jẹ ki orileede yii goke agba ko si tun ni ilọsiwaju, ki wọn mu ọrọ ẹlẹyamẹya kuro ninu gbogbo nnkan ti wọn ba fẹẹ ṣe, bi bẹẹkọ wahala nla lo maa n fa.

Ọkunrin naa sọrọ yii niluu Abẹokuta lakooko to n ba awọn oniroyin fọrọ jomitoro ọrọ. 

O sọ pe ko yẹ ki aṣaaju orileede maa fi apa kan da apa si lorileede yii nipa iyanipo to ba pa gbogbo wọn pọ.

O fikun ọrọ ẹ pe bijọba to wa lode lakooko yii ṣe n ṣe lori ọrọ ẹlẹyamẹya lori eto ọrọ aje le mu akude bawọn.

Ṣowumi ẹni to ti figba kan gbe apoti ibo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun,tun ṣalaye siwaju pe  àwọn aṣáájú òṣèlú àtawọn olókìkí ní àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ olóṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe lè kọ ìjọba lọ́nà tootọ́ àti ọ̀nà aridájú tó lè mú kawọn ìlànà ìjọba tiwa-n-tiwa pọ̀ sí i, dípò kíkópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tàbí ìpayà tí yóò tún pín orílẹ̀-èdè náà níyà.

O waa rọ Aare Tinubu lati tu awọn ibi to ti fawọn gusu  to wa ni iwọ-oorun jẹ gaba lori” eto-ọrọ aje ka ,ko si ṣe iwọntunwọnsi ipinisipo sawọn ibi to yẹ, lati le  mu ifọkanbalẹ ba orilẹ-ede wa.

Bakan naa lo sọ idi pataki to fi da ẹgbẹ ‘The Alternative’ silẹ iyẹn lati yanju awọn ewu to wa ninu awọn ọrọ ẹya kaakiri orilẹede yii.
Lori ipo alaga ẹgbẹ lapapọ, Ṣowumi sọ pe oun nikan lo si koju oṣuwọn toun le mu ayipada rere bawọn.
O sọ pe ka ni awọn amọran toun ti gba wọn lati ẹyin wọn tẹle ni, o ṣee ṣe ki ẹgbẹ ọhun ti pada sipo alaṣẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages