Lati le jẹ kawọn fayawọ ti wọn ko ẹru ofin wọlu le mọ pe ọga agba fawọn ẹṣọ aṣọbọde tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Mohammed Salisu Shuaib ko waa ṣere rara, laarin ọsẹ perete to bẹrẹ iṣẹ, o ti foju awọn fayawọ tọwọ tẹ han eemọ pẹlu ẹru ofin ti wọn gba lọwọ wọn.
Gẹgẹ bo ṣe ṣafihan lakooko ipade oniroyin to waye ni Idi-iroko, nipinlẹ Ogun lo tun ti tẹnumọ ọn pe ko saaye fawọn to yan iṣẹ fayawọ laayo nipinlẹ naa mọ ati pe gbogbo ọna lawọn yoo gba lati maa gbena woju wọn.
O fikun ọrọ ẹ pe laarin ọṣẹ perete ọhun ẹru ofin tọwọ wọn tẹ fẹẹ to miliọnu igba le lọgbọn naira.
Lara awọn ẹru ofin ọhun ni mọto tokunbọ 2012 Toyota Highlanders, apo irẹsi oni kilo aadọta, ẹgbẹrun meji le ni ogoje, apo igbo ẹgbẹrun kan le ni ọgọfa.
Awọn yooku tun ni bata aloku ẹgbẹrun mẹrin le ni ọgọfa, taya, kẹẹgi epo pẹtiroolu atawọn nnkan mii.
Shaibu tun ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi iṣẹ tawọn gba lati maa dena awọn to n ko ẹru ofin wọlu lọna aitọ, ti wọn si fi n ba ọrọ aje, awọn ti ṣiṣẹ takuntakun lati le jẹ ki wọn mọ pe awọn ko bawọn ṣere rara lati fi ipinlẹ Ogun silẹ.
O ni labẹ ọga awọn wọn pata lorileede yii, Bashir Adewale, o ti fawọn lawọn ilana ati igbesẹ lati ma ṣiṣẹ wọn,eyi tawọn si n ṣe pẹlu ootọ inu.
O tun fikun un pe lara awọn agbegbe tawọn ti gba ẹru naa ni Idi-iroko, Ilaro, Ọbada oko, Alamala Rounder, ni Abẹokuta, Abule Kazeem ati Imẹkọ-Afọn.
O waa lo akoko naa lati sọ fawọn eeyan ipinlẹ Ogun paapaa julọ awọn ọlọja pe ki wọn fọkanbalẹ nitori awọn ti wọn ba ni ẹru ofin lawọn maa n gbena woju.
O ṣeleri pe ileeṣẹ aṣọbode yoo tubọ tẹsiwaju lati ṣiṣẹ wọn lọna ti ko ni farani araalu.
No comments:
Post a Comment