Ilu Ibadan yoo gbalejo ayẹyẹ ọ̀ṣọ́ orí lagbaaye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 15 December 2024

Ilu Ibadan yoo gbalejo ayẹyẹ ọ̀ṣọ́ orí lagbaaye




Gbogbo eto lo ti to bayii fun ayẹyẹ ọṣọ ori lagbaaye eyi ti ẹgbẹ kan ti wọn ti forukọ ẹ silẹ labẹ ijọba, iyẹn Ọmọ Yoruba Atata Socio-Cultural initiative (ỌYASI) ṣagbatẹru akọkọ iru ẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọgbẹni Ọlawale Ajao, to jẹ alaga igbimọ agba fun ayẹyẹ ọhun fi sita lo ti ṣalaye pe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun yii ni eto naa yoo waye ni gbọngan Single Tennis Court, to wa ni papa iṣere Lekan Salami, Adamaṣigba, niluu Ibadan.

O ṣalaye pe pataki ayẹyẹ ọhun ni igbelarugẹ ọṣọ ori lati inu aṣa wa wọ agbaye ni eyi ti ajọ agbaye UNESCO yoo ṣatẹwọgba ẹ lati maa ṣayajọ ẹ lọdọọdun.

O fikun ọrọ ẹ pe awọn olukopa bii ẹgbẹrun meji lati awọn ẹya jakejado ni wọn yoo kopa pẹlu awọn ọṣọ ori ti yoo ṣafihan ibi ti wọn ti wa.

Lara erongba wọn ti wọn fi ṣagbekalẹ eto yii gẹgẹ Ọgbẹni Ajao ṣe tan imọlẹ ẹ ni lati mọ ipa ti ọṣọ ori kọọkan n ko ninu aṣa wa.

Bẹẹ lati ti le jẹ kawọn eeyan mọ nipa agbara ti ọṣọ ori n ko lọna ti wọn fi paroko lawujọ.

O sọ pe pẹlu ọṣọ ori tawọn olukopa ba yan laayo ni wọn yoo fi jokoo lọjọ naa.Alagba Alao Adedayọ, alaga patapata fun ileeṣẹ iwe iroyin Alaroye ati Alaroye tẹlifiṣan lori ẹrọ ayelujara ati Alaaji Oriyọmi Okikiọla Hamzat ni yoo gba awọn eeyan lalejo.

Dokita Wasiu Ọlatubọsun,kọmiṣanna fọrọ aṣa ati irinajo afẹ nipinlẹ Ọyọ, ni olugbalejo agba nigba ti Ọba Akinloye Owolabi Ọlakulẹhin, Olubadan tiluu Ibadan ni yoo gba awọn ori ade yooku lalejo.

Lara awọn ọba alaye to tun bọ ni Ọba Abdulrashed Adewale Akanbi, Oluwoo tilu Iwo,Ọba Sẹfiu Ọlawale Oyebọla, Aṣẹyin tiluu Isẹyin ati Olori ẹ, naa n bọ wa sibi ayẹyẹ yii.

Awọn ti yoo da wọn lẹkọọ lọjọ naa ni Dokita Ọlalẹyẹ Samuel Kayọde, lati ẹka ti wọn ti  kọ ẹsin, ni ọgba yunifasiti Ibadan.
Alagba Alao Adedayọ ati onimọ nipa ẹsin islam nni, Sheik Taofeek Akewugbagold

Ohun tawọn idanilẹkọọ ọhun yoo si duro lori ni iṣọkan lori aṣa ati agbara to wa ninu ọṣọ ori, ati itumọ tọpọ ẹ mu dani.

No comments:

Post a Comment

Pages