Ọga asọbode tuntun to ṣẹṣẹ gba ipo, nipinlẹ Ogun, Mohammed Shaibu, ti kilọ fawọn fayawọ lati yẹra patapata nipinlẹ ọhun nitori awọn yoo tẹsiwaju lati maa gbena woju wọn.
Ọkunrin naa sọrọ lakooko to n gba ipo lọwọ ẹni to wa nibẹ, James Ojo, ẹni to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ naa bayii, o sọ pe gbogbo ọna loun atawọn to wa labẹ oun yoo fi rii pe fayawọ dinku patapata.
O sọ pe oun ṣetan lati maa ran awọn to ba n ṣiṣẹ lọna to ba ofin mu lọwọ, nitori ki iṣẹ wọn ba le maa lọ siwaju. Amọ ẹni to ba ko ẹru ofin wọle, tọwọ ba tẹ yoo rugi oyin laisi ojuṣaaju.
Shaibu to ti figba kan adari ikọ ti wọn sọ ẹnu ibode, ti wọn ti fofin de tun ṣeleri pe gbogbo iriri toun ni loun yoo lo nipo tuntun yii lati le jẹ ki ileesẹ aṣọbode tubọ gberu sii.
O waa gboriyin fun ọga to gba iṣẹ lọwọ ẹ, James Ojo fawọn aṣeyọri to ṣe atawọn ipilẹ to fi silẹ lati tẹle.
Ọga agba ọhun wa lo akoko naa lati bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn ikọ alaabo yooku nitori o agbajọ ọwọ la n fi sọya.
Ko to to akoko naa ni James Ojo, to fipo ọhun silẹ ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ore ọfẹ to fun oun bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ awọn ọmọọṣẹ lori bi wọn ṣe fọwọsowọpọ pẹlu oun.
Ko sai tun lo akoko naa lati dupẹ lọwọ awọn ikọ alaabo atawọn ọba alaye nipinlẹ Ogun bẹẹ lo tun rọ wọn lati fọwọsowọpọ pẹlu adari tuntun yii.
No comments:
Post a Comment