Ẹgbẹ ọdọ niluu Agbado iyẹn Agbado youth forum ti fi idunnu wọn han lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, to wa niluu Ibadan lori bi wọn ṣe ni ki Akintoye Akinrinade to jẹ ọmọ Baalẹ ọhun to ti di oloogbe, Anthony Akinrinade maa tẹsiwaju ninu ẹjọ wahala ọrọ ọlọbade to n waye niluu naa.
Gẹgẹ bi ọrọ ti Olumuyiwa Amọdu, to jẹ alaga fẹgbẹ ọhun ṣe sọ nibi ayẹyẹ opin ọdun ti wọn ṣe niluu Agbado, ni wọn ti fi imọ riri wọn han, eyi to si jẹ ki wọn nigbagbọ pe awọn yoo jawe olubori, ti Akintoye yoo si di ọba ilu ọhun laipẹ.
Nibi ayẹyẹ ọhun tawọn eeyan jakanjakan to fi mọ awọn olori ẹṣọ abo ti peju pesẹ ni alaga naa tun ti sọ pe ni nnkan bi ọdun marun-un sẹyin tile ẹjọ giga ti gbe idajọ kalẹ sibẹ ọba to wa lori oye ko mu aṣẹ ṣẹ nipa pipe ara ẹ ni ọba ti wọn ni ko gbọdọ pe ara ẹ.
O ni eyi lo jẹ kile ẹjọ kotẹmilọrun fi n ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ lati le jẹ ki idajọ ododo waye.
Amọdu ṣalaye siwaju pe' Nibi taa ti n ba igbẹjọ ọhun lọ ni Baalẹ wa, Anthony Akinrinade ti jade laye, eyi lo mu ki awọn agbaagba ilu,to fi mọ awọn baalẹ, ọlọja atawọn ọdọ ṣe forikori lati wa ẹni ti yoo rọpo ki ẹjọ ọhun fi le tẹsiwaju"
O ni inu awọn dun lati darukọ Akintoye Akinrinade gẹgẹ bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe tẹwọgbaa ni ọgbọnjọ oṣu kẹwaa, ọdun 2024, lati tẹsiwaju igbẹjọ naa.
Amọdu tun fikun ọrọ ẹ pe lati nnkan bi ọdun marundinlogoji niluu Agbado ti n dun yungba gẹgẹ bi ilẹ ọrọ aje ati okoowo, ko to waa di pe awọn kan de ti wọn wa da wahala slẹ lati dori gbogbo nnkan kodo.
O waa ni pataki ajọyọ wọn ni lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun bẹẹ lo si tun wa fun irẹpọ ati iṣọkan to n jọba laarin wọn.
Ninu ọrọ ti Ọmọọba Akintoye Akinrinade fi sọwọ si wọn lo ti jẹ ki wọn mọ pe bo tilẹ jẹ pe irọ ti n lọ bi ogun ọdun, oun mọ pe akoko ti to ti ootọ yoo farahan, o ni kawọn araalu lọ fọkanbalẹ.
No comments:
Post a Comment