PDP Ogun yẹyẹ Ladi Adebutu lori oye to jẹ, Wọn ni arumọjẹ ni - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 2 November 2024

PDP Ogun yẹyẹ Ladi Adebutu lori oye to jẹ, Wọn ni arumọjẹ ni


Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, ti kesi oludije wọn fun ipo gomina ninu ibo to kọja, Ọnarebu Ladi Adebutu, lati dẹkun kiko idọti ba ẹgbẹ naa nita gbagba nitori ohun itiju nla ni.

Ninu atẹjade ti Austin Oniyokor, to jẹ akọwe olupongo fẹgbẹ naa fi sita lorukọ alaga ẹgbẹ ti igun ọdọ wọn, Ọnarebu Sikirulae Ọlawale Ogundele, ni wọn ti kilọ fun Adebutu, ko sowo ọmọ agbejẹ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni gbogbo ọpọ awuyewuye ati iyapa lo ti fẹẹ n waye lori oye arumọjẹ ti Ladi ati iyawo ẹ jẹ gẹgẹ bi Aṣiwaju Odogbolu lọjọ Tọsidee, ọsẹ yii.

Atẹjade ọhun sọ pe" O ṣe ni laanu pe lakooko ti nnkan ko rọgbọ tawọn araalu ko rowo fi jẹun ni Adebutu waa na milọnu lori oye ti gbogbo awọn eeyan gan an mọ si arumọjẹ, ki wọn le mọ pe o wa nibẹ.

"Ko ba dara ko fi owo naa ṣe nnkan ti yoo mu idunnu wọle, a tiẹ dupẹ pe o gba amọran wa taa fun, to si ti ṣeleri pe oun yoo da ibikan silẹ ti wọn yoo ti maa kọṣẹ silẹ lagbegbe"

PDP Ogun sọ pe itiju nla lo jẹ fawọn pe igbimọ lọbalọba ti Odogbolu Alaye lodi si oye ọhun ti wọn ko si yọju sibi ayẹyẹ naa.
Wọn ni idi abajọ ree to fi jẹ pe inu yara ijokoo Ọba Adedeji Oluṣẹgun Ọnagoruwa, Alaye ti Odogbolu ni wọn ti joye ọhun.
Atẹjade ọhun tun sọ pe ko ya awọn lẹnu pe gbogbo fidio ati aworan ti wọn fi han kaakiri ko ju Adebutu ati iyawo ẹ ti wọn joye, ọpọ awọn oloye atawọn eeyan jakan niluu ni wọn ko yọju, abuku nla ni wọn pe e.

Idi niyii ti wọn fi sọ pe awọn kilọ fun Adebutu ko ye mu abuku wa fawọn mọ, nitori ẹgbẹ PDP, ti kọja nnkan ti wọn ko lero

No comments:

Post a Comment

Pages