Lanre Oyegbọla-Ṣodipọ, oludije alaga nijọba ibilẹ Abẹokuta North, di ẹru jẹjẹ mọ awọn yooku ẹ lọwọ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 2 November 2024

Lanre Oyegbọla-Ṣodipọ, oludije alaga nijọba ibilẹ Abẹokuta North, di ẹru jẹjẹ mọ awọn yooku ẹ lọwọ.



Ki i ṣe tọrọ ẹnu mọ pe ko ju perete mọ ti ibo ijọba ibilẹ yoo waye nipinlẹ Ogun, eyi ti wọn fi si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii.

 Bẹẹ lọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn fẹẹ dije ti n polongo kaakiri.

Ṣugbọn eyi to jọ ni loju, to si yanilẹnu  ni bi Lanre Ọyagbọla-Ṣodipọ, ọkan lara awọn oludije fun ipo alaga ijọba ibilẹ ọhun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nijọba ibilẹ Abẹokuta North, ṣe waa di ẹru jẹjẹ mọ awọn yooku ẹ lọwọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, latigba ti ọkunrin naa ti jade lati dupo, ni ọpọ awọn eeyan ijọba ibllẹ ọhun to fi mọ agba oṣelu ti nigbagbọ ninu ẹ pe oun nikan ni Ọlọrun tun le lo lati mu ki idagbasoke ati ilọsiwaju ba kansu wọn nibẹ.

Nitori ẹ ni ko ṣe ya awọn eeyan lẹnu nigba ti wọn gbọ pe oun ni  Gomina Dapọ Abiọdun atawọn agba ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ naa fa kalẹ lati dije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Bi wọn si ti ṣe faa kalẹ la gbọ pe awọn eeyan agbegbe naa ti fi ẹgbẹ oṣelu APC lọkanbalẹ pe ko sewu fun wọn mọ nitori aayo wọn ni fun wọn, o si di dandan kawọn ṣagbatẹru ẹ lati fi ibo wọn gbe e wọle.

A tiẹ n sọ ni latigba ti ipolongo ti bẹrẹ nijọba ibilẹ Abẹokuta North, o fẹẹ jẹ pe oun nikan ni wọn rii pe o muu ni ọkunkundun nipa lilọ ati bibọ ẹ, to si jẹ kawọn araalu mọ awọn erongba rere to ni fawọn eeyan ẹ, ti wọn ba fi ibo gbe e wọle.

Bakan naa lo si n tẹnumọ pe iṣẹ rere ti Gomina Dapọ Abiọdun ti n ṣe kaakiri, ti to lọtọ lati fi ṣe awokọṣe fawọn nnkan toun ni lọkan , toun si gbadura pe ki Ọlọrun muṣẹ.

Ni bayii, Lanre Ọyagbọla-Ṣodipọ ti sọrọ soke, o ni bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun gbogbo igba toun yoo lo gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ, lẹyin ti wọn ba dibo foun, ko nii ba ewu de, nitori nnkan to ti wa lọkan oun ni lati sin awọn eeyan oun lọna ti yoo mu inu wọn dun.

 


1 comment:

  1. Seen him in my ward (ward 13)I believe is a Man of integrity.God Almighty will help you Sir.

    ReplyDelete

Pages