Bi ibo ijọba ibilẹ ṣe n sunmọ nipinlẹ Ogun bẹẹ naa ni awọn eeyan ijọba ibilẹ Abẹokuta North si n fọkan Lanre Ọyagbọla Ṣodipọ, oludije fun ipo alaga ijọba lbilẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Lara ẹ ni tawọn ara agbegbe Oke- Ọna ti wọn ṣeleri fun oludije naa lati fi ọkan balẹ lori ibo ọhun ati pe gbogbo wọn ṣetan lati fọwọsowọpọ ṣiṣẹ fun.
Nibi ipade ti oludije naa ṣe pẹlu awọn eeyan wọnyii ni wọn ti sọ pe idaniloju wa pe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo jawe olubori.
Ninu ọrọ ti Lanre lọjọ naa lo ti kọkọ dupẹ lọwọ wọn fun atilẹyin ti wọn ṣe fun APC latẹyin wa, to si tun ke si wọn lati tubọ tẹsiwaju.
O sọ pe ibo ti wọn fẹẹ di na ti alajọbi ni ki wọn si rii pe gbogbo wọọdu to wa ni Oke Ọna ni ki wọn dibo wọn oun atawọn kanselọ ti wọn jade ninu ẹgbẹ APC.
O fikun ọrọ ẹ pe oun dupẹ lọwọ Gomina to fun wọn ni ore ọfẹ ti alaga to dije ti agbegbe naa, ki wọn ma jẹ ki anfani ọhun fo wọn ru.
Bakan naa lo tun lo akoko naa lati fi sọ awọn nnkan to ti gbese fun wọn lagbegbe naa atawọn to tun lọkan lati ṣe fun wọn to ba jawe olubori.
Bẹẹ lo nijọba oun mọ ọn mọ ni eto fawọn arugbo atawọn ọdọ bakan naa tọwọ wọn ko fi ni dilẹ.
Kọmureedi Tijani to sọrọ lorukọ awọn agbegbe mọkandinlogun to wa labẹ mu oludije alaga naa loju pe didun ni ọsan yoo so fun wọn lọjọ ibo.
Bẹẹ ni kọmureedi Baṣiru rọ Lanre lati ma ṣe gbagbe awọn agbegbe yooku.Lara awọn to wa nibẹ ni Alaaja Adesanya,Ọnarebu Oluwọle, awọn oludije kanselọ ati Alaaja Ọlọpẹ.
No comments:
Post a Comment