Awọn ara Abẹokuta North ti sọrọ:Lẹyin Lanre Ọyagbọla- Ṣodipọ ko si oludije miii - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 10 November 2024

Awọn ara Abẹokuta North ti sọrọ:Lẹyin Lanre Ọyagbọla- Ṣodipọ ko si oludije miii




Bo tilẹ jẹ pe o ku ọsẹ kan ti ibo ijọba ibilẹ yoo waye tawọn oludije kaakiri ipinlẹ Ogun si ti n gbaradi,awọn olugbe ijọba ibilẹ ti sọ pe lẹyin Lanre Ọyagbọla- Ṣodipọ ko tun si oludije miii tawọn mọ fun ipo alaga ijọba ibilẹ.

Ọkunrin yii to tun jẹ oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ni wọn ti fi lọkanbalẹ pe ko sewu loko longẹ oludije ọhun nitori awọn iṣẹ to ti ṣe silẹ ti fihan gẹgẹ bi ẹni to kaju ẹ.

Gbogbo ibi ti Lanre de ni wọn ti kan sara sii gẹgẹ bi ẹni to kaju ẹ, to si le tubọ mu kijọba ibilẹ tẹsiwaju.

A o ranti pe lọjọbọ Tọsidee, to kọja yii ni oludije ọhun ṣepade pọ pẹlu awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to fi mọ awọn olori agbegbe ti wọn wa labẹ ijọba ibilẹ ọhun, nibi to ti kọkọ dupẹ lọwọ wọn fun atilẹyin ti wọn ṣe fun Gomina Dapọ Abiọdun ati ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ.

Bakan naa lo mẹnuba awọn ipinnu ẹ fun ijọba ibilẹ Abẹokuta North, eyi ti yoo tubọ mu igbe aye dẹrun fawọn olugbe ọhun paapaa nipa eto ilera, ẹkọ, ironilagbara, bẹẹ lo jẹ ki wọn mọ pe itọju awọn arugbo ṣe koko ninu ijọba oun.

Lanre tun jẹ kawọn eeyan ẹ mọ pe ilana Gomina Abiọdun lati fi tun ipinlẹ Ogun ṣe lori eto IṢẸ YA, bẹẹ loun yoo ṣamulo e nijọba ibilẹ Abẹokuta North.

Eyi lo wa jẹ kawọn olugbe ijọba Abẹokuta fi oludije naa lọkanbalẹ ati pe ninu gbogbo oludije yooku, oun nikan lawọn mọ pe o ṣetan lati di alaga wọn pẹlu adura pe Ọlọrun yoo gbe debẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages