Alaga fẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, nipinlẹ Ogun, Abioro Temitayọ, la gbọ pe o ti kọwe fipo silẹ bayii.
Gẹgẹ bi lẹta ifipo silẹ tọkunrin naa kọ si alaga ẹgbẹ naa lapapọ niluu Abuja, Ralph Okey Nwosu, eyi to fi ẹda ẹ sọwọ si wa lo ti sọ di mi mọ pe oun ti gbe ipo ọhun silẹ fun ẹni ti ẹgbẹ ba mọ pe o le gba akoso.
O kọkọ dupẹ fun ifọwọsowọpọ ẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ fun anfaani ti wọn foun lati le lo ọpọlọ ẹ lati dari ẹgbẹ naa wa.
O sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC yii jẹ eyi toun nifẹẹ si gidi pẹlu awọn agbekalẹ, to si jẹ eyi to wa nipo keji, ninu ibo 2023, to kọja yii.
Itunu tun ṣalaye pe" Igba kan maa n wa teeyan yoo joko ti yoo da ronu pe n jẹ ipo ti mo wa yii, ṣe mo le tẹsiwaju si,paapaa julọ tawọn eeyan ba n beeere si?"
O ni bo tilẹ wu oun lọkan lati kopa to jọju ninu ẹgbẹ oṣelu to yan laayo yii, amọ eleyii ko le ṣee ṣe nitori bi oun ṣe nifẹẹ ẹgbẹ oṣelu yii denu, toun si fẹran agbekalẹ ati aṣa to wa ninu ẹ pẹlu awọn to wa nibẹ lati wọọdu de ijọba ibilẹ.Paapaa julọ fun oludije wọn ninu ibo ijọba ibilẹ to kọja yii.
O sọ pe " Ohun idunnu ati aṣeyọri nla lo jẹ fun mi lati da ogo ẹgbẹ oṣelu ADC pada bọ sipo lati ọdun 2023 ibo gbogbogboo titi di ọdun 2024, apẹẹrẹ rere nla lo jẹ fun mi."
O waa sọ pe pẹlu idunnu ati ayọ loun ṣe n fi ipo ọhun silẹ tawọn aṣeyọri oun toun ṣe yoo mu itọpasẹ rere lati tẹle fẹni ti wọn ba fi rọpo ẹ.
No comments:
Post a Comment