Àjọ aṣọ́bodè fa ògùn olóró tí wọn rí gbà lé NDLEA lọwọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 22 November 2024

Àjọ aṣọ́bodè fa ògùn olóró tí wọn rí gbà lé NDLEA lọwọ




Ọga agba fun ajọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, James Ojo, tun ti sọ pe digbi lawọn wa lati ri pe opin de ba kiko ẹru ofin wọlu bẹẹ lawọn ko nii foju awọn fayawọ balẹ.

O sọrọ yii lakooko to n ṣafihan awọn ẹru ofin tọwọ wọn ba atawọn aṣeyọri ti wọn ti ṣe.

Lọjọ naa ni ọga agba yii fa ogun oloro to le ni ẹgbẹrun meje ti wọn ri gba le ajọ to n gbogun ogun oloro iyẹn NDLEA lọwọ.

Lakooko to n fa le wọn lọwọ, James Ojo sọ pe awọn ogun oloro yii towo ẹ fẹẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira lawọn ri gba laarin ọjọ kẹtala oṣu kẹwaa si ọjọ kẹtala, oṣu kọkanla, ọdun yii.

O fikun ọrọ ẹ pe lawọn agbegbe kan niluu Abẹokuta, Agbawọ, Igankoto ni ariwa Yewa nijọba ibilẹ Imẹkọ-- Afọn, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti ri awọn ogun oloro ọhun gba.

Bẹẹ lo tun lo akoko lati fi kilọ fawọn fayawọ ti wọn ko awọn ogun oloro wọlu lati tete yi ipinnu wọn pada nitori awọn ko nii foju re wo awọn tọwọ ba tẹ.

Ọga agba aṣọbode tun dupẹ lọwọ ọga wọn pata lorileede yii, Adewale Adeniyi,lori atilẹyin ẹ to n ṣe, nipasẹ ẹ lo ni awọn fi ṣaṣeyọri.

Bẹẹ lo tun lo akoko naa lati fi tọrọ ifọwọsowọpọ awọn araalu, ki wọn jọ le gbogun tawọn ti wọn fẹẹ ko ogun oloro wọlu.

Nigba to n tẹwọ gba awọn  ogun oloro ọhun, Ọgbẹni Oluṣẹgun Adeyẹye, to jẹ adari ajọ to n gbogun ti ogun oloro, gboriyin fun ajọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, fawọn iṣẹ ribiribi ti wọn ti ṣe lori igbogun tawọn fayawọ lawujọ.

Bẹẹ lo ṣeleri atilẹyin nla fawọn aṣọbode ni gbogbo igba ti wọn ba ti n fẹ ẹ.Bakan naa lo ni awọn ṣetan lati bẹrẹ iwadii wọn lati le rọwọto awọn to n ṣiṣẹ ibi yii.

No comments:

Post a Comment

Pages