Lẹyin ọdun mẹrinlelogoji ti Ayinla Ọmọwura ku:Kasnanty ṣawari iku to pa a - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 29 September 2024

Lẹyin ọdun mẹrinlelogoji ti Ayinla Ọmọwura ku:Kasnanty ṣawari iku to pa a

 

 

 Ninu oṣu karun-un ọdun yii to kọja lọ yii, lo pe ọdun mẹrinlelogoji, ti ọba awọn olorin apala nni Ayinla Ọmọwura, jade laye, tọpọ awọn eeyan si ti ṣiṣẹ lori nnkan to ṣokunfa iku aitọjọ ti wọn lo mu ọkunrin ọhun lọ nigba naa.

 

Bawọn kan ṣe sọ pe igo ti manija ẹ, ti wọn pe ni Bayewumi fọ mọ ọn lori nigba to fẹẹ lọ gba mọto fẹẹsipa to gbe fun un lo mu ẹmi ẹ lọ nigba naa, eyi to mu ki wọn dajọ iku fun manija naa.

 

Amọ ni bayii, gbajumọ sọrọsọrọ nii Kọlawọle Adejojo, tọpọ mọ si ‘Kasnanti Sugar’, ti ṣe alabapade baba agbalagba kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Adisa Ilelabaewe, to jẹwọọ pe oun loun pa Ayinla Ọmọwura, nitori oruka ẹrẹ toun ṣe fun –un to fi gba aya, lo fa iku ojiji naa.

 

Gẹgẹ bi baba naa ṣe wi, o sọ pe ko sigba toun ba ranti iku Ayinla Ọmọwura ti inu oun ki i ba jẹ, nitori oun mọ pe ki i ṣe igo ti Bayewumi fọ mọ-ọn lori lo pa a bi ko ṣe orukan naa ati pe awọn to mọ nipa ẹrọ ẹ ko si nitosi.

 

Alagba ilelabaewe ṣalaye pe ‘’Ẹgbọn mi ni Ayinla Ọmọwura ni Itoko, o jẹ ẹni ti mi ko le fọrọ ẹ ṣere,ko sawọn ilu bii Kano, Kaduna, Jos atawọn ilu mii to lọ, ti mi o ki i ba wọn lọ.

 

‘’ Loootọ mi o ki i ṣe elegbe wọn o, bi wọn ti fẹẹ ṣere, mi o ni jokoo ti wọn o, ma a ṣe bi ẹni ti ko mọra ri, bo ba ṣi ti n kọrin, mo maa dide lọ nawo fun u. Tawọn kan ba wa ba mi pe ki n kuro niwaju ẹ, ki lo de, ṣe ọmọ ilu ni mi ni, mo maa wa sọ fun wọn pe, ko ṣe ma nawo fun un ni,olorin daadaa ni.

‘Ṣe ni wọn yoo ti mi danu, ti wọn yoo ma nawo fun un, nigba taa ba dele, wọn yoo da owo mi pada fun mi, nitori wọn ko ni ko mọ owo ti wọn gba.

Lori oruka to sọ pe oun ṣe fun Ayinla nigba naa, baba naa sọ pe, ‘’Oniṣegun ni mi latilẹ, ko si sẹni ti ko mọ mi, mo wa ninu ẹni to fun Ayinla ni ikilọ, ṣugbọn ti ko gbọrọ si mi lẹnu. Mo rẹ oruka to ṣe e ja, mo ba si fun ni ẹyọ kan.

‘’Oruka yẹn ni gbẹrẹ ti wọn gbọdọ sin si ẹsẹ osi, iyẹn jẹ gẹgẹ bi ẹrọ, bi wọn ba ṣẹ eeyan ni ẹṣẹ kan, to ba fi oruka naa gba a, ti ko ba fi ẹsẹ osi yẹn gba onitọhun, iku de niyẹn.

Nipa ibeere ti wọn beere lọwọ ẹ pe nnkan tawọn eeyan sọ ni pe igo ti Bayewumi fọ mọ ọn lori, lo muu ku iku ojiji nigba naa, Ilelabewe sọ pe, ki i ṣe igo, nitori ti Ayinla fi oruka naa gba aya, lo mu ko ṣubu lulẹ.

Nigba ti wọn waa beere lọwọ ẹ pe,  ṣe ka sọ pe ẹyin ni ẹ gba Ayinla, esi to fi dahun ni pe, ‘’Ọwọ mi lo  ti wa, ka ni mo mọ ni, mi o nii ṣe oruka yẹn fun. Nitori wọn ki i fii kan aya, ati pe ka ni awọn to mọ ẹrọ ẹ ba wa nitosi ni, wọn a ti fi ẹsẹ kan ara wa pada, ti yoo si dide pada’’

O ni titi di akoko yii ni iku ọba olorin apala naa fi n dun mi, latigba naa loun ko ti ṣe iru oruka bẹẹ mọ. Nigba ti wọn beere lọwọ ẹ pe bawo lo ṣe mọ pe oruka to fun Ayinla lo pa a.

Esi to fi dahun ni pe ‘’Nigba ti wọn wa ba mi pe baba, Ayinla Ọmọwura ti ku o,emi naa wa lọ si ọsibitu lati lọọ woo, mo ba oruka ọhun ni ọwọ rẹ, ohun ni mo fi mọ. Emi tiẹ n wo yii, ni mo n ṣawo fun n nigba to wa laye.

O waa ni ẹkọ toun kọ ninu iṣẹlẹ naa ni pe gbogbo iṣẹ teeyan ba n ṣe, ti ko ba dara, ko yaa tete jawọ ninu ẹ.

Show quoted text

No comments:

Post a Comment

Pages