Ẹgbẹ oṣelu ADC ti ṣetan lati jawe olubori ninu ibo ijọba ibilẹ to n bọ - Abioro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 28 September 2024

Ẹgbẹ oṣelu ADC ti ṣetan lati jawe olubori ninu ibo ijọba ibilẹ to n bọ - Abioro


  


Ọgbẹni Itunu Abioro, alaga fẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, nipinlẹ Ogun, to tun jẹ alukoro fun ẹgbẹ apapọ oloṣelu iyẹn IPAC, ti sọ pe awọn ti gbaradi fun ibo ijọba ibilẹ ti yoo waye laipẹ yii ati pe idaniloju wa pe awọn yoo jawe olubori.

Lakooko ti ọkunrin naa ba oniroyin wa sọrọ lo ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe oriṣi idojukọ lawọn n ba a pade lati ọdọ ajọ eleto idibo OGSIEC, nipinlẹ naa lori owo kanpa ti wọn ni kawọn san, tọrọ naa si ti wa nile ẹjọ, sibẹ, awọn yoo ma tọ awọn ilana to yẹ lati gbe.

 

Alaga ọhun tun sọ pe, ‘’Ohun ti awa apapọ ẹgbẹ oloṣelu duro le lori, ni nnkan ti iwe ofin to di gbogbo wa mu paapaa awa oloṣelu lorileede yii.

‘’Fun apẹẹrẹ, iwe ofin sọ pe ẹnikẹni to ba fẹẹ dibo gbọdọ jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun bẹẹ naa ni ẹni to ba fẹẹ dije dupo naa gbọdọ jẹ ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn. Ṣugbọn ohun taa ri ni pe ni iwe ofin tipinlẹ Ogun, ọgbọn ọdun lo wa nibẹ, bẹẹ niwe ofin ti wọn tun sọ pe ẹni to ba fẹẹ dije dupo gbọdọ niwee ẹri owo ori, amọ iwe ofin ilẹ wa ko sọ bẹẹ.

‘’Bẹẹ ni iwe ofin wa ko sọ pe ki oludije sanwo fun ẹnikẹni lati dibo niwọngba ti wọn ba iwe ẹri oniwe mẹwaa lọwọ, o lẹtọọ lati dije fun ipokipo to ba wu u’’.

‘’Ẹgbẹ oṣelu ADC ti kọ lẹta si ajọ eleto idibo OGSIEC ni aimọye igba pe, ti wọn ko ba dẹyin lẹyin owo tipatipa yii awọn yoo gbe wọn lọ sile ẹjọ. Ẹgbẹ apapọ oloṣelu naa ti ṣepade pọ pẹlu awọn ọmọ igbimọ aṣofin lori ọrọ yii lati bawọn sọrọ pe gbogbo nnkan ti wọn n ṣe ko tọna.

‘’O dabi ẹni pe agbara awọn aṣofin gan-an ko fẹẹ ka wọn tabi ajọ eleto idibo ọhun lo kọ eti ikun si nnkan ti wọn ba wọn sọ.

Abioro sọ pe nitori naa ni apapọ ẹgbẹ oṣelu IPAC, ti gbe ajọ OGSIEC lọ sile ẹjọ lọna meji ọtọọtọ, ọkan ni Kobapẹ,l’ Abẹokuta ati ẹlẹẹkeji ni Abuja.

O fikun ọrọ ẹ pe bo tilẹ jẹ pe ọrọ ti wa nile ẹjọ amọ, awọn yoo ṣi maa ṣe gbogbo nnkan to yẹ, lati gba fọọmu ati awọn nnkan to yẹ ki a ṣe, ile ẹjọ ni yoo wa pada wa ba wọn da si.

O ni ẹgbẹ ADC ni oludije kaakiri fun ipo alaga ijọba ibilẹ ati kanselọ lawọn wọọdu kaakiri, bẹẹ lawọn si ti n polongo ara wọn fawọn araalu nipinlẹ Ogun.

 O ṣalaye siwaju sii pe bo tilẹ jẹ pe gbogbo nnkan to yẹ ki wọn ni ki awọn ṣe, lawọn tẹle amọ awọn jẹ ko ye OGSIEC pe ilana ti wọn gbe idibo naa gba ko tẹ wa lọrun.

O ni, ‘’Awa n ṣe ti wa gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere, nitori a bọwọ fun ofin. Ẹgbẹ oṣelu waa ti bẹrẹ ipolongo, emi gan-an naa ti bẹrẹ, emi funra ni naa si ti n gori afẹfẹ, ibi taa ti n polongo ibo naa la n sọ fun araalu pe ka ni awa la wa nijọba ni, a ko ni jẹ ki wọn ri idaamu bayii.


No comments:

Post a Comment

Pages