Ìwà àìbíkìtà Ládi Adebutu ló mú ìfàsẹ́yìn bá PDP Ògùn- Ogundele - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 25 August 2024

Ìwà àìbíkìtà Ládi Adebutu ló mú ìfàsẹ́yìn bá PDP Ògùn- Ogundele



Oloye Sikirulai Ogundele, alaga tẹlẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, nipnlẹ Ogun ti sọ oju abẹ nikoo pe iwa aibikita oludije wọn fun ipo gomina, Ọnarebu Ladi Adebutu, lo jẹ kawọn padanu lẹẹmeji ọtọọtọ to jade dupo.

Lakooko to n ba oniroyin sọrọ, o sọ pe iwa adari ẹgbẹ ko si lọdọ ọkunrin naa, to si ti mu ifasẹyin ba PDP nipinlẹ Ogun.

O ṣalaye pe ẹni ti ko ba si ti ni awọn nnkan ti wọn fi ṣee ko le mu aṣeyọri ba ẹgbẹ.O ni awọn ibo mejeeji ti Adebutu ti dupo gomina, o fihan gbangba pe ko ni ipo ọhun ṣe, o kan mọ ọn mọ fi wọn pawo si apo ara ẹ.

Ogundele tun sọ pe" Nigba naa lọhun, gbogbo awọn agba ẹgbẹ lo ba ja to le kuro ninu ẹgbẹ nitori pe o fẹẹ dije, ko si le dun mi nitori owo baba ẹ lo n na, to si maa n sọ pe baba oun ni gomina wu, ki i ṣe oun"

O fikun ọrọ ẹ pe gbogbo eleyii ni lawọn ẹgbẹ da ro ti wọn fi sọ pe ẹlẹẹkẹta to sọ pe oun tun fẹẹ lọ ayafi ki wọn tete gbe igbesẹ.

O tun sọ pe, " PDP ki i ṣe ile baba ẹnikan debi ti yoo fi jẹ pe Ladi nikan ni yoo maa gbe apoti gomina, nigba ti OGD fẹẹ dupo lọdun 2002, awọn mẹtadinlogun ni wọn jade ti wọn ṣe pamari fun. Ṣe ni a rii pe ko fẹẹ ki wọn ma ba oun duu, bẹẹ ogun baba ẹnikan kọ ni ẹgbẹ"

Ogundele ni aimọye igba lawọn ti baa sọrọ, to jẹ pe ọtọ ni nnkan ti yoo ṣe lonii,to ba tun di ọla, ọtọ ni yoo ṣẹlẹ.

Gbogbo ẹ lo sọ pe awọn ro papọ pe nnkan ko le maa lọ, nitori awọn mọ pe awọn ti ṣubu nibi ibo to ti n waye,awọn si n gbiyanju lati dide.

O ni" Eyi to buru ninu ẹ ni pe lẹyin ọjọ keji taa gba idajọ lori ibo to kọja ni Ladi tun ti pariwo pe oun fẹẹ dije lẹẹkẹta,ti gbogbo wa si mọ pe gomina to wa nipo bayii, to n lo ọdun kẹjọ lọwọ, Rẹmọ kan naa lawọn mejeeji ti jọ wa nijọba ibilẹ kan naa, ṣe ti wọn ba di wa, awa naa ko gbọdọ di ara wa"

Alaga PDP tẹlẹ naa tun sọ awọn ko fi gbogbo ara nigbabọ ninu awọn igbimọ fidihẹ ti wọn ṣẹṣẹ yan nipinlẹ Ogun, nitori bi wọn ṣe n jo siwaju bẹẹ naa ni wọn jo rẹyin tawọn si ti fi ọrọ naa to awọn oloye ẹgbẹ l'Abuja leti tawọn si mọ pe wọn yoo gbe igbesẹ, to ba yẹ ko to di pe ipade gbogbogboo yoo waye.

O ni bi gbogbo awọn ṣe mọ pe oloṣelu ki i sinmi, bi Ọlọrun ba fẹ, oun yoo dije lẹẹkeji fun ipo alaga naa.

No comments:

Post a Comment

Pages