Ọkan lara ọdun ti wọn ki i fi ṣere niluu Oworonṣoki, nipinlẹ Eko, ni Ọta jẹ, eyi to so gbogbo tonile ati alejo papọ.
Idi niyii ti wọn fi ṣayẹyẹ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, to kọja, nibi ti wọn ti kọkọ ṣe awọn etutu kan ko to di ọjọ naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, anjọnu inu omi ni ọta yii jẹ, to si jẹ ooṣa to maa n mu idagbasoke wọnu ilu.
Ọkan lara ooṣa ti wọn ko le gbagbe nilu ọhun ni Ọta omi jẹ, ti wọn si ti n ṣe lati bi ọdun meloo kan ṣẹyin.
Ọdun mẹta ni wọn maa n ṣe ọta niluu Oworo ṣugbọn ti Ọba Saliu Owolabi Saliu ti paṣẹ pe ki wọn maa ṣe lọdọọdun.
Ko to di pe ayẹyẹ ọhun waye ni gbogbo awọn ọmọ ilu naa, to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC New Era, eyi ti aarẹ ẹgbẹ wọn, Rasak Arogundade atawọn ọba alaye, ti Ọba Saliu Owolabi Saliu, ṣaaju wọn lọ sibi odo, nibi ti wọn ti kọkọ lọ ṣetutu.
Nibẹ lawọn ọdọ ti wa ninu aṣọ funfun ninu ọkọ oju omi, pẹlu ooṣa ọta ọhun ti wọn si n yi odo nla naa kan pẹlu oriṣiiriṣii orin ajọdun naa.
Lẹyin naa ni oluwo ilu Oworo, Oloye Suraju ati Ọba Saliu fi omi ati ọti ṣadura nibi ojubọ ọhun, ko to di pe wọn pada sibi ayẹyẹ ọhun.
Ninu ọrọ Ọba Saliu,Oloworo tilu Oworo, o dupẹ lọwọ gbogbo awọn to wa sibi ayẹyẹ naa bẹẹ lo gba wọn niyanju lati maa gbe aṣa atawọn oriṣa wa larugẹ.
O sọ pe ki i ṣe pe awọn ṣẹṣẹ n sọdun naa, o ti wa lati aye awọn babanla wọn ati ọdun mẹta mẹta ni wọn maa n ṣe tẹlẹ amọ latigba toun yii lọ ọdọọdun ni wọn yoo maa ṣe.
Bẹẹ lo jẹ ki wọn mọ pataki ọdun ọta naa gẹgẹ bi eyi to n mu alaafia ati idagbasoke wọlu. Bakan naa ni Kabiyesi tun mẹnuba bi wọn ṣe ṣẹ wa si ilu Oworonṣọki ti wọn wa lonii.
Ninu ọrọ ti Rasak Arogundade, aarẹ ẹgbẹ OPC New Era, ti wọn ṣagbatẹru ayẹyẹ ọhun lo ti ṣeleri pe gbogbo igba lawọn yoo maa ṣe igbelarugẹ aṣa iṣẹmbaye ilẹ Yoruba nitori o jẹ awọn logun.
Bakan naa lo rọ gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba pe ojuṣe wọn ni lati maa ko ipa to jọju fun awọn iranti awọn ooṣa wa.
O sọ di mi mọ pe ọdun pataki ni ọta jẹ nilu Oworonṣoki, eyi to tun maa n mu ki irẹpọ wa laarin tonile talejo to n gbe niluu naa.
Gbajumọ olorin fuji nni, Ṣẹfiu Alao, lo ṣere fun wọn lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment