Lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii nileesẹ iwe iroyin BO ṢE RI, ọkan lara iwe iroyin to n gbe ẹwa ati aṣa Yoruba larugẹ fun Olu tilu Itori, Ọba AbdulFatai Akorede Akamọ, ni ami ẹyẹ Alayeluwa ọrẹ awọn akọroyin.
Ayẹyẹ idanilọla naa lo waye niluu Itori lakooko ti wọn ṣe ayẹyẹ ojude ọba, eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun, nibẹ lawọn eeyan pataki lawujọ to fi mọ awọn ọba alade ti waa ba Olu Itori ṣajọyọ ayẹyẹ ọhun.
Ninu ọrọ Ọgbẹni Johnson Akinpẹlu to ṣaaju ikọ awọn oniroyin yooku lọ sibẹ lo ti ṣapejuwe Ọba Fatai Akamọ, gẹgẹ bi ẹni ti ki i fi fawọn oniroyin ṣere, to si jẹ pe ọpọ igba lo maa n jẹ ipe wọn ti wọn ba ti pe bẹẹ.
Bẹẹ lo tun gborinyin fun ọba naa lori bo ṣe gba ifẹ, isọkan ati alaafia laye nilu ọhun ati fawọn ohun idagbasoke to ṣee fojuri to ti ṣe latigba to ti de alefa bẹẹ lo ni orukọ ọmọ lo maa n ro gẹgẹ bi ọrọ awọn Yoruba, O ni Akorede ti Ọba naa n jẹ tun jẹ ko ko awọn oore wọlu, to fi jẹ pe iwaju niluu wa wa bayii.
Akinpẹlu tun fikun pe o loju awọn ọba naa, to le ko awọn oniroyin mọra bi Ọba Akamọ ṣe maa n ṣe, ati pe Alayeluwa ọrẹ awọn akọrọyin ti wọn fi da a lọla yii ko bẹbẹ ẹ bi ko ṣe pe iwa ati iṣẹ to ti ṣe ni wọn ro mọ ọn lara.
Ninu ọrọ Oloye Johnson Onifade, toun naa jẹ agba ọjẹ nidii iṣẹ iroyin lo ti sọ pe ninu gbogbo awọn ọba toun ti mọ nipinlẹ Ogun, Ọba Akamọ jẹ ẹni akọkọ ti kii fọrọ awọn oniroyin ṣere, ati pe ko sibi to ba ti pade yin, ki i foju paayan rẹ, tẹrin tọyaya lo maa n ṣe.
Nigba to fi idunnu ẹ han lori ami ẹyẹ ọhun, Ọba Fatai Akamọ dupẹ lọwọ awọn oniroyin ti wọn wa yẹ oun si lọjọ naa. O ni eyi fihan pe gbogbo nnkan ti ẹda ba n ṣe ko maa ṣe daadaa nitori ere ẹ si n bọ. Bẹẹ lo wa ṣeleri lati maa tẹsiwaju ninu ajọṣepọ to danmọran laarin oun atawọn oniroyin gbogbo
Olorin waka nni, Alaaja Salawa Abẹni lo forin da awọn eeyan lọla nibi ayẹyẹ ojude ọba ọhun.
No comments:
Post a Comment