Ogo atijọ ṣi ni OPC n lo, ayẹyẹ ọgbọn ọdun kọ lo kan lakooko yii- OPC NEW ERA - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 11 July 2024

Ogo atijọ ṣi ni OPC n lo, ayẹyẹ ọgbọn ọdun kọ lo kan lakooko yii- OPC NEW ERA


Ẹgbẹ OPC New Era ti sọ pe ko si nnkan to n jẹ ayẹyẹ ọgbọn ọdun lakooko yii, nitori ogo atijọ ni wọn si n lo, ati pe bi wọn ṣe da ẹgbẹ ọhun silẹ nigba naa kọ lo wa bayii, ati pe bi ọrọ aje orileede yii ṣe ri ko mu inu eeyan dun lati ṣe iru nnkan bẹẹ.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Abiọdun Alex Adeṣina fi sita, eyi ti aarẹ ẹgbẹ naa, Oloye Rasak Arogundade Balogun fọwọ si lorukọ ẹgbẹ naa ni wọn ti sọ pe awọn yapa patapata si ajọdun ọgbọn ọdun idasilẹ ẹgbẹ naa, eyi ti Ọtunba Gani Adams, Aarẹ Ọna Kankanfo atawọn eeyan n gbero.

Gẹgẹ bi wọn  ṣe wi, wọn ni latigba ti Gani Adams atawọn eeyan ẹ ti fi erongba ẹ lati ṣayẹyẹ ọhun lawọn ti n gba oriṣi ipe lori foonu atawọn atẹjiṣẹ. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko kaa kun tẹlẹ,  nitori awọn rii gẹgẹ bi ọna ti ọkunrin yii fi n fẹ polongo ara ẹ, ki wọn le mọ pe oun ṣi wa amọ awọn jade fesi kawọn araalu le mọ bo ṣe n lọ.

OPC New  Era tẹsiwaju pe awọn ṣi wa lori ọrọ wọn pe awọn ti le olori wọn yii danu kuro ninu ẹgbẹ OPC ati pe gbogbo awọn ti wọn si n tẹle tabi ba a dowo pọ si n tan ara wọn jẹ ni, wọn ni ko si ibi ti iru ayederu eeyan bẹẹ ko si yala nini lọya, dokita, babalawo ati bẹẹbẹẹ lọ, ko si iṣẹ ọhun to wa ki wọn ma ni kanda inu irẹsi bẹẹ.

Bakan naa OPC New era tun sọ pe pẹlu bi ọrọ aje ṣe n lọ lorileede yii yoo ṣoro lati ma pariwo pe ki iru ayẹyẹ bẹẹ waye niwọngba to jẹ pe awọn naa n tako iru igbesẹ bẹẹ lọdọ awọn to n fẹ ṣe e lakoko ti ilu ko dun, ko tun wa jẹ pe awọn ni wọn yoo wa ba nibẹ, ko le ṣee ṣe.

Bẹẹ ni wọn tun fikun ninu ọrọ wọn pe ọpẹlọpẹ ipa tawọn OPC atawọn ajafẹtọọ mii-ii ko lo jẹ ki orileede yii ni ijọba tiwa-n-tiwa. Wọn ni nnkan ti idasilẹ OPC wa fun nigba naa ni lati gbogun tijọba oloogun ti wọn jẹ gaaba, pẹlu awọn ti wọn sa kuro lorileede yii, awọn si sa ipa wọn titi ti wọn fi bori lọdun1999.

New Era tun ṣalaye siwaju pe ohun to waye nigba lakooko ibo aarẹ nigba ti Aarẹ tẹlẹ lorileede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Oloye Olu Falae, fi pade nibi ibo aarẹ to waye mọ.

Wọn waa ni ki Ọtunba Gani Adams bọ sita ko waa sọ awọn aṣeyọri to ti ṣe laarin ọdun mẹwaa sẹyin ninu ẹgbẹ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages