Ọga kọsitọọmu nipinlẹ Ogun sabẹwo sọdọ Alake tilẹ Ẹgba, atawọn ọba alaye mii-ii - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 5 July 2024

Ọga kọsitọọmu nipinlẹ Ogun sabẹwo sọdọ Alake tilẹ Ẹgba, atawọn ọba alaye mii-ii-Bẹẹ lo tun lọ sọdọ awọn alaabo yooku

 

Laipẹ yii ni ọga awọn aṣọbode nipinlẹ Ogun, James Ojo, ṣe abẹwo lọ sọdọ Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ,atawọn ọba alaye kan, bẹẹ lo si tun lọ sawọn ileeṣẹ alaabo yooku ti wọn wa nipinlẹ naa, lati le jẹ ki ajọṣepọ to danmọran wa laarin wọn, ati lati wa ọna bi eto ọrọ aje yoo tun ṣe gberu si lawọn ẹnu bode ati orileede Benin to mu ile ti wọn lẹgbẹ.

 

 

Ninu atẹjade ti Bukunoye Oloyede, to jẹ agbẹnusọ fun ajọ ọhun fi sita lo tan tan imọlẹ si gbogbo irinajo naa lo si aso rere. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni lakooko to de afin Alake  tilẹ Ẹgba, niluu Abẹokuta,o kọkọ dupẹ lọwọ Ọba Gbadebọ fun awọn atilẹyin, ti wọn si n kopa gẹgẹ bi ọba alaye lati le jẹ ki alaafia jọba, ti wọn si n gba ki eto aabo danmọran lawọn agbegbe wọn.

 

Ojo wa lo anfaani naa lati tan imọlẹ pataki ipa awọn ọba alaye lati le jẹ ki abo wa lawọn ẹnu bode ati lati le gbogun tawọn onifayawọ lawọn agbegbe to yi wa ka. Bẹẹ ni ọga agba ọhun tun ṣe ipade ọlọkan-ọ-jọkan pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo,nibi ti wọn ti jọ jiroro lori ipenija ati ọna abayọ lori awọn fayawọ.

 

Nibẹ lo ni wọn ti panupọ lati wọ ọna ti wọn yoo gba doju ija kọ awọn ti wọn ba ọrọ aje orileede yii jẹ. Irinajo abẹwo to ṣe kaakiri yii lo nii ṣe pẹlu aba ti ọga agba wọn patapata nibi to ti rọ wọn lati rii pe wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo yooku, eyi ti yoo mi ki alaafia jọba ni ayika, ti abo yoo si wa.

 

Bakan naa ni Ojo tun jẹ ki wọn mọ pataki idi ti wọn fi gbọdọ ṣiṣẹ pẹlu Benin, ati bi wọn yoo ṣe wa nisọkan lati gbogun tawọn fayawọ lori ọrọ aje. O waa mu da gbogbo wọn loju pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ lati le mu agbega ba ọrọ aje wa.

 

Gbogbo awọn ti ọga asọbode yii sabẹwo de ọdọ wọn ni wọn mu daa loju pe awọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn. Lara awọn ileeṣẹ alaabo to de ni tawọn ọlọpaa, ologun, ẹṣọ oju ọna,agbofinro, ọgba atunṣe atawọn yooku.

 

No comments:

Post a Comment

Pages