Ileeṣẹ aṣọbode Ogun tun ṣe aṣeyọri nla nipa pipa owo wọle - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 8 July 2024

Ileeṣẹ aṣọbode Ogun tun ṣe aṣeyọri nla nipa pipa owo wọle

Ọga agba fun ileeṣẹ aṣọbode nipinlẹ Ogun, James Ojo tun ti sọ nipa aṣeyọri nla ti wọn ṣe ni ẹka ipa owo wọle si osuwọn ijọba fun saa keji ọdun yii.

Nibi ipade oniroyin ti wọn ṣe niluu Abẹokuta lọjọ Aje, Mọnde ana, lo ti fi idunnu ẹ han pe miliọnu mejilelaadọrun, ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun ati igbalemẹtadinlọgbọn naira lawọn pa a wọle.
O ṣalaye pe ida  mejilelaadọta lo fi ju ti saa keji ọdun to kọja lọ.Ninu eyi ti wọn ti pa miliọnu mejilaadọta,ẹgbẹrun mẹsan-an le mẹtalelọgọrin ati ẹgbẹta le mejilelogun naira ti wọn pa lọdun 2023.

O sọ pe ileeṣẹ ọhun fi miliọnu mẹrinlelọgbọn, ẹgbẹrun lọna ọgọfa le meji ati ẹgbẹta o le naira ju iye ti wọn ni lọkan lati pa a wọle fun oṣu keji ọdun 2024.
James Ojo tun fikun ọrọ ẹ pe ọrọ ẹ pe awọn nnkan to jẹ kawọn pa owo wọle koju ifarajin ati ifọkansi tawọn ṣe pẹlu iṣọkan.

O ni pẹlu afikun ipawowọle yii tun je ki ileeṣẹ aṣọbode tun jẹ kawọn nipa ninu eto idagbasoke ọrọ aje lorileede yii.

Bakan naa lo tun mẹnuba awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn fayawọ bii apo igbo,ọta ibọn loriṣiriṣi, apo irẹsi, aloku taya mọto ati ọkada, tọọki atawọn nnkan mii -ii.

O ni bi awọn ṣe gba awọn nnkan wọnyii lọwọ fayawọ fihan iṣẹ takuntakun tileeṣẹ ọhun ṣe lati gbogun tawọn to n ba ọrọ aje waa jẹ.

O waa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ awọn ọba alaye atawọn ileeṣẹ alaabo yooku fun ajọṣepọ to danmọran ati atilẹyin nla tawọn ri gba, to jẹ kawọn ṣe aṣeyọri nla yii.

Bẹẹ lo ni ileeṣẹ ọhun yoo tẹsiwaju lati sa ipa wọn lori igbogun tawọn fayawọ kaakiri.

No comments:

Post a Comment

Pages