Iyafin Bọla Ọbasanjọ, aya aarẹ orileede yii tẹlẹ ti gba awọn obi nimọran lati ma ṣe wo ti ipenija to n waye, ki wọn rii pe ọjọ iwaju awọn ọmọ wọn ṣe pataki.
Bẹẹ lo tun rọ wọn lati ma wo ti ebi tabi owo iranwọ ti wọn yọ lori epo ti wọn pe ni sọbsidi, ki wọn rii pe wọn sa gbogbo agbara wọn lati ran ọmọ wọn nileewe.
O sọrọ yii nibi idanilẹkọọ ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹẹkejila iru ẹ tileewe Lyceum to waye ni ọgba ile ikawe Oluṣẹgun Ọbasanjọ, iyen OOPL, niluu Abẹokuta.
O gba wọn niyanju lati rii pe wọn mu ala awọn ọmọ yii ṣẹ nipa ki wọn le dẹni pataki lọjọ iwaju.
Iyawo Ọbasanjọ tun wa gboriyin fawọn obi nipa bi wọn ṣe ran awọn ọmọ lọ sileewe Lyceum pelu bi owo wọn ṣe ga soke, o waa gbadura fun wọn pe wọn ko nii ṣe lasan lori awọn ọmọ yii.
Bẹẹ lo tun rọ awọn obi atawọn alagbatọ lati ma ṣe tori bi ilu ṣe le koko yi ipinnu wọn pada lati waa mu awọn ọmọ wọn kuro nileewe.Pẹlu adura pe ki Ọlọrun gbe ọwọ wọn soke.
Ninu ọrọ Arabinrin Moureen Ọla Williams, to jẹ olori ileewe ọhun lo ti rọ awọn obi ati alagbatọ lati kọ ọmọ wọn lọna ti wọn fi n bọwọ fawọn olukọ atawọn aṣaaju lawujọ, nitori ko le baa wulo fun wọn lọjọ iwaju.
Bẹẹ naa ni Dokita Yinka Ọla Williams gba awọn obi nimọran lati jẹ ki wọn ni ibẹru Ọlọrun lọkan, ki wọn si sun mọ ọn pẹlu
No comments:
Post a Comment