OmoobaJamiu Ademoye, ERE OSUPA
Gbogbo ilu lgboko lo kun fofo to n dun yungba fun ayeye odun marun un igbade Oba Alayeluwa Yusuf Olamilekan ltu, llemobade ll, kiniun Dawo ljatele 1, Onigboko ti ilu lgboko Awori Lusada -Igbesa, ipinle Ogun.
Ayeye olose meji naa waye pelu olokan ojokan eto bii : Ifinijoye, lsese, ere ldaraya, ljo ibile, sisi Aafin igbalode ti Onigboko, ati bee bee lo.
Leyin orisirisi eto, asekagba eto waye ni ojo kokanlelogbon, osu karun un odun 2024 .
Gbogbo inu Ileewe alakoobere ti Orile lgboko ibi ayeye naa lo kun fun obitibiti awon eniyan pataki nile yii ati loke okun.
Bee lawon Ori ade pese biba sibi ayeye manigbagbe naa. Ninu oro ikini kaabo, Oba Onigboko, Alayeluwa so pe ayeye naa waye lati dupe fun Eledumare ati lati se afihan awon aseyori lati odun marun un seyin.
Lara awon aseyori naa ni atunko Ojo Lusada, atunse ninu Ile -Iwe Orile lgboko alakoobere, kiko afin igbalode ti Onigboko, Igbese fun kiko lleewe girama Oba Olabode Memorial High School ( Free , Eko ofe) , ati awon miran to le mu awon Ile wa fun idagba soke ilu lgboko.
Siwaju asekagba, Lara awon Oloye tun ba awon oniroyin soro, Alhaja Olubukola Rukayat, iya oba so ohun iwuri nipa kabiesi, bee naa ni Oloye khadijat Amope , to je Erelu so nipa ife ati ifowosopo pelu kabiesi, ti Yeye Ewa Olajumoke Adunni n gbero lati ran awon opo ati odo lowo fun itesiwaju ilu lgboko.
Awon Oba alaye naa gbe oriyin fun Oba Onigboko fun aseyori nla laarin odun marun un, Lara awon Oba naa ni Oloto ti ilu Oto Awori,Oba Dr. Josiah Aina Ikuyamiku, Alayeluwa Olofin Adimula ti Ado-Odo so wipe Ajosepo to dan maran wa pelu Onigboko tohun tipe awon paala pelu ilu lgboko.
Kabiesi dupe lowo awon Baale, Oloye, gbogbo Ebi lapapo ati Ara ilu lgboko fun Ajosepo ati aduroti.
Kabiesi dupe lowo awon Ori Ade to wa fun ayeye naa bii: Oba Timi lati Ede, Oba Oniba, Oba Ademola Elegushi, Olu ti idi Oke, Oba Oniru, , Oba Oniwoye, Oba Olobere ti ilu Ota, Oba Akesan, ati awon ladelade nikale
Oba Orin Wasiu Ayinde k1 lo fi ilu dabira ti gbogbo re dun yungba lojo naa
[
No comments:
Post a Comment