Ọnarebu Abdulrasheed ọmọ Kashamu ṣe bẹbẹ fawọn eeyan lọjọ ọdun ileya - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 16 June 2024

Ọnarebu Abdulrasheed ọmọ Kashamu ṣe bẹbẹ fawọn eeyan lọjọ ọdun ileya



 

 

Gẹgẹ bi ayẹyẹ ọdun ileya ṣe n lọ lọwọ, Ọnarebu Abdulrasheed Kashamu, to n jẹ ọmọ Oloogbe Buruji Kashamu, to tun ṣoju ẹkun Ijẹbu North, nile Igbimọ aṣofin, nipinlẹ Ogun, ṣe bẹbẹ fawọn to n ṣoju fun nigba to pa wọn lẹrin ayọ ti wọn ko ro tẹlẹ.

 

Nibi eto ọhun to waye lonii ọdun ileya nile ẹ to wa ni Ijẹbu-Igbo, nibẹ lo ti fawọn eeyan ni owo ati ounjẹ ti wọn mu lọ sile kawọn eeyan ọhun naa le sọdun ayọ.

 

Gẹgẹ bi awọn Yoruba ṣe maa sọ pe ẹni to bi ni laajọ, idi niyii tawọn eeyan to jẹ anfaani awọn ẹbun naa ṣe n kan sara si ọmọ Kashamu yii to tun jẹ olori awọn ọmọ igbimọ aṣofin to kere julọ ọhun.

 

Bẹẹ ni wọn tun gboriyin fun un lori bo ṣe gbe igbesẹ ti baba ẹ gbe nigba to wa laye nipa riran awọn to ba ku diẹ kaato lọwọ, lori awọn ẹbun ti wọn ko ro tẹlẹ yii ti ẹni to kere ju nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun yii fun wọn.

 

Iwadii fi ye wa pe lati nnkan bi aago mẹsan-an aarọ ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn,to jẹ  ọmọ ile igbimọ aṣofin ti de si yidi to wa ni Oke Alafia, Atikori, Ijebu Igbo, nibi to ti lọ kirun.

 

Bi o si ti de lo ti paṣẹ pe ki wọn ṣilẹkun abawọle oun silẹ lati fawọn eeyan laaye lati wọle ki wọn wa ba oun ṣe ajọyọ ọdun ileya naa. Nibẹ ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii ti fawọn eeyan ni ounjẹ ati ẹbun owo to ti wa ninu apo iwe fun ẹnikọọkan.

 

Ninu ọrọ ẹ to ba awọn oniroyin sọ ni Kashamu ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani ati oore-ọfẹ to fun oun lati ri ọdun ileya to waye lonii.

 

O sọ pe lati le tẹsiwaju awọn iṣẹ rere ti Baba oun, Buruji Kashamu fi silẹ, awọn ṣeto lati ran ẹgbẹrun mẹjọ awọn eeyan lọwọ lawọn agbegbe to yi wọn ka laifi ti ẹsin tabi ẹlẹyamẹya tabi oṣelu ṣe.

 

O ni ayẹyẹ ti wọn ṣe ọhun jẹ pataki fun ọdun ileya, bẹẹ lo waa pe ipe fun isọkan, ati alaafia awọn eeyan ki wọn si jọ maa gbe ni irẹpọ.

No comments:

Post a Comment

Pages