Ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party ti Ogun East ti ṣeleri pe awọn ti ṣetan lati jọ ṣiṣẹ pọ fun ilọsiwaju.
Ọrọ yii waye nibi ipade ti wọn ṣe niluu Ijẹbu Ode, nibi tawọn alaga atawọn akọwe nijọba ibilẹ to wa ni ẹkun naa peju pesẹ.
Ninu ọrọ Ọmọkẹhinde Olowu, to jẹ akọwe olupolongo ẹgbẹ yii nipinlẹ Ogun, to tun jẹ ọmọ agbegbe naa lo ti sọ pe pataki ipade wọn ni lati jọ jiroro lori bi ilọsiwaju yoo ṣe de ba ẹgbẹ ọhun.
Bẹẹ lo ti kọkọ ki awọn oloye ẹgbẹ naa lori awọn ipa ti wọn ti ko sẹyin, o tun waa rọ wọn lati ma ṣe fa sẹyin, ki wọn si rii pe ẹgbẹ naa gbegba oroke ninu ibo ọdun 2027.
Olowu tun fi idunnu ẹ han lori bawọn eeyan ṣe n jade forukọ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ tuntun bẹẹ lo rọ wọn lati tubọ bẹrẹ si ni polongo NNPP kaakiri awọn wọọdu.
Ninu ọrọ Ọnarebu Funṣọ Jide Adekunle, to jẹ alaga ẹgbẹ ọhun fun ẹkun naa lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan ẹ yii fun atilẹyin ti wọn foun nipa bi ẹgbẹ naa ṣe n gbooro si.
Ohun naa tun wa rọ wọn lati pada sijọba ibilẹ wọn lati tẹsiwaju ninu iṣẹ wọn pẹlu adura pe wọn yoo jere nigbẹyin.
Lara awọn to tun wa nibẹ ni Ọmọọba Micheal Adesanya, Ajihinrere Kunle Sodiji
Arabinrin Yetunde Aina, Mallam Shuaibu ati Ọnarebu Fatai Adenaya.
No comments:
Post a Comment