Ẹgbẹ oṣelu NNPP Ogun tun awọn oloye ẹgbẹ tuntun mii-ìì - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 29 June 2024

Ẹgbẹ oṣelu NNPP Ogun tun awọn oloye ẹgbẹ tuntun mii-ììẸgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party, tipinlẹ Ogun, ti darukọ Ọnarebu Foluṣọ Adekunle, tọpọ mọ si Fussy, gẹgẹ bi olori awọn ọdọ tuntun fẹgbẹ ọhun.

Nibi ipade ẹgbẹ naa to waye lọjọ Ẹti, Furaide ana, ni Olowu ọmọKẹhinde to jẹ akọwe olupolongo ẹgbẹ naa ti darukọ ọkunrin naa ninu atunto to ṣẹṣẹ deba awọn oloye wọn.

Lara awọn ti wọn tun darukọ ni Ọmọọba Micheal Adesiyan to di alaga fun ẹkun Ogun East, Ọnarebu Ohio Faith ati Kọmureedi Ọlaoluwa Akinsọla.

Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ naa nibi ipade naa, Agbẹjọro Fẹmi Aina, ki awọn eeyan naa ku oriire bẹẹ lo tun rọ wọn lati ma ṣe ja awọn eeyan nitanmọ igbagbọ ti wọn ni ninu wọn.

Bẹẹ lo tun fi idunnu ẹ han lori bi iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ tuntun ṣe n lọ lọwọ nipinlẹ naa ati bi awọn eeyan ṣe n tu jade lati wa darapọ mọ wọn.

O fikun ọrọ ẹ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii o ti fihan pe loootọ ati lododo lawọn  araalu nifẹẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP ati pe laipẹ yii ni ayẹyẹ igbaniwọle yoo waye.

O waa rọ awọn oloye ẹgbẹ naa lawọn ijọba ibilẹ ati wọọdu lati tubọ mura si iṣẹ wọn, ki wọn si rii pe ohun gbogbo n lọ bo ṣe yẹ.

Fẹmi Aina tun waa tẹnumọ pe ifẹ ati iṣọkan lawọn n fẹ lakooko yii, ki wọn si ma ṣe gba awọn mọdaru laaye saarin wọn

No comments:

Post a Comment

Pages