Gbogbo eto lo ti to fun ti ayẹyẹ ọdun ileya, eyi tẹgbẹ oṣelu NNPP fẹẹ ṣe lọjọ keji ileya.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọnarebu Fatai Adenaya fi sita, Mosadawọni House, ni Ilushin, Ogun Waterside ni yoo ti waye nibi tawọn olorin ọlọkan ọ jọkan yoo ti da awọn eeyan lara ya.
Lara awọn ti wọn n reti lọjọ naa ni awọn agba ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu NNPP jakejado ipinlẹ Ogun kaakiri.
Pataki ayẹyẹ ọhun ni lati fi idunnu han si Ọlọrun to jẹ ki wọn ri ọdun naa layọ ati alaafia.
No comments:
Post a Comment