Ayẹyẹ ọdun kan:Awọn iyawo aṣofin nipinlẹ Ogun fi ẹbun tọrẹ fawọn ọmọ alainiya l"Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 21 June 2024

Ayẹyẹ ọdun kan:Awọn iyawo aṣofin nipinlẹ Ogun fi ẹbun tọrẹ fawọn ọmọ alainiya l"Abẹokuta


Lati fi ṣe ami ọdun kin in ni tawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun ẹlẹkẹwaa dori oye, awọn iyawo wọn ṣe bẹbẹ nigba ti wọn lọ fẹbun ta awọn ọmọ alainiya ti Stella Ọbasanjọ, to wa ni Ibara, niluu Abẹokuta lọrẹ.

Dokita Ọlayinka Ẹlẹmide, to jẹ iyawo olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun lo ṣaaju awọn iyawo ọnarebu yooku lọ.

Ninu ọrọ ẹ, Arabinrin naa sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati fi ẹmi imoore han to fawọn ọkọ wọn lati ṣayẹyẹ ọdun kan naa ọhun ati lati dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun pe o pese aṣaaju rere fun wọn.

Bakan naa lo sọ pe oun atawọn yooku waa sile awọn ọmọ alainiya naa lati mu inu awọn ọmọ naa dun pẹlu.

Dokita Ẹlẹmide tun ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi a ṣe mọ awọn ọmọde ni ọjọ iwaju orileede ti wọn yoo si di rere lọjọ iwaju.

Bẹẹ lo tun wa gboriyin fawọn olutọju awọn ọmọ naa, bo tilẹ jẹ pe ko rọrun amọ awọn gba a ladura pe ki Ọlọrun de iṣẹ wọn lade.

O ni " Gbogbo wa la mọ pe awọn ọmọde yii ni ọjọ ọla wa, mo gbadura pe laala yin lori awọn ọmọ naa ko nii ja si asan, ohun kan to jọju lati ṣe fawọn ọmọ yii ti inu wọn fi le dun ni ka mu ẹbun wa fun wọn,nitori ijọba nikan ko le da a ṣe, awọn ẹlẹyinju aanu gbọdọ ṣatilẹyin fun wọn."

O waa fi akoko naa rọ awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ lati maa dide iranwọ si gbogbo awọn ile ọmọ alainiya to wa kaakiri.

Iyawo Ẹlẹmide tun wa dupẹ lẹẹkan si lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun fun bo ṣe gba alaafia laaye laarin awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ati lọwọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin fun ifarajin wọn lati le jẹ ki idagbasoke ba ipinlẹ Ogun.

Lara awọn ẹbun ti wọn fi tọrẹ ni irẹsi, awọn ipapanu, ẹlẹrindodo atawọn nnkan mii-ii

No comments:

Post a Comment

Pages