Wọn fi ayẹyẹ ọjọọbi Yọmi Fabiyi pari ija ọlọjọ pipẹ laarin Yinka Quadri ati Ogogo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 3 May 2024

Wọn fi ayẹyẹ ọjọọbi Yọmi Fabiyi pari ija ọlọjọ pipẹ laarin Yinka Quadri ati Ogogo


Ohun kan waye nibi ayẹyẹ onibeji ti gbajumọ oṣere tiata nni Yọmi Fabiyi, ṣe lọjọruu, Wẹsidee, ọpọ awọn to wa nibẹ lo si n ya lẹnu pe ṣe iru nnkan bẹb le maa waye, ki wọn si fi ṣe oku oru laarin ara wọn, ko to di pe o lu sita lọjọ naa.

Ayẹyẹ ọjọọbi ati iṣile ni oṣere Yoruba ọhun ṣe lọjọ naa, bo tilẹ jẹ pe adura ni wọn iṣile ni wọn fi kọkọ bẹrẹ eyi to waye ni ojule keje, opopona Adifagbọla, ìlu Abẹokuta. 

Asiko adura naa ni aafaa to ṣe waasi lọjọ naa ti sọ pe ki gbogbo awon eeyan to wa nibẹ ṣadura fun mama to bi Yọmi to ti doloogbe, ninu ọrọ aafa naa lo ti sọ pe daadaa ti Iya Yọmi ṣe silẹ́ ni ọmọ ẹ jọla ẹ lonii. Ṣe ni Yọmi bu sẹkun rangbọndan, ti baba ẹ to jokoo sẹgbẹ ẹ rẹ ẹ lẹkun.

Gbogbo awọn eeyan to wa nibẹ ni wọn mọ pe iku mama ẹ si n ka a lara di asiko yii. Lẹyin adura ni wọn


ni ayẹyẹ jijẹ ati mumu   waye ni gbọngan nla kan,ti wọn pe ni Emfelix, to wa lọna abule Mecho, Idi- Aba, niluu Abẹokuta, nibi ti gbajumọ olorin fuji nni, Sule Alao Malaika ti ṣere fawọn eeyan..

Nibẹ gan-an ni aṣiiri nla kan ti tu sita sawọn to wa nibẹ. Agba oloriki nni Alagba Ajobiewe ni wọn pe sita lati wa fi ẹbun ẹ yẹ oninawo ọjọ naa si, a fi bo ṣe pe agba oṣere nni Yinka Quadri sita, bẹẹ lo pe Ogogo naa, to si fi ewi ẹnu paroko sawọn agba oṣere mejeeji naa lati pari gbogbo aawọ to wa laarin awọn mejeeji lati bi ọdun meloo kan sẹyin.

Ṣe lọpọ awọn to wa nibẹ bẹrẹ si nii woju ara wọn pe ṣe awọn agba oṣere mejeeji, ti wọn ti jọ n ṣe bọ lati bi ọpọ ọdun sẹyin n ba ara wọn ja, ti ko si lu sita. Ọjọ naa ni Ajobiewe bẹ awọn mejeeji ki wọn gbagbe nnkan to ti waye lati ẹyin, ki wọn pada si bi wọn ṣe n ṣe tẹlẹ.

Ki awọn eeyan fi le mọ pe o ti tan, o ni kawọn mejeeji dimọ ara wọn, lẹyin naa ni wọn tun nawo fun Baba oloriki ọhun. Gbogbo awọn oṣere naa ni wọn sọrọ iwuri nipa Yọmi, wọn ni akinkanju eeyan ti ki i fẹ ki wọn rẹ ọmọlakeji ẹ jẹ lọkunrin  naa, wọn ni ọkunrin naa fẹran ọmọlakeji ẹ ju ara ẹ lọ.

No comments:

Post a Comment

Pages