Nitori ipo gomina Ogun: Yayi bura niwaju Muyideen Bello l"Ekoo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 5 May 2024

Nitori ipo gomina Ogun: Yayi bura niwaju Muyideen Bello l"Ekoo

O ti han gbangba pe gbogbo ọna ni Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla tọpọ mọ si Yayi, to n ṣoju ẹkun Ogun West lọwọlọwọ bayii n wa lati le fi di gomina nipinlẹ Ogun, lọdun 2027.

Irufẹ niṣẹlẹ to waye nibi ayẹyẹ oniwaasi nni Ami Ọlọrun, nibi ti oniwaasi agbaye, Sheik Muyideen Bello, ti sọ pe ki ọkunrin naa jade sita lati waa bura lori ipo gomina to n lepa yii.

Sẹnetọ Adeọla ẹni ti wọn fi ṣe alaga nibi ayẹyẹ mọṣalaṣi tuntun ti Amin Ọlọrun ṣẹṣẹ kọ, to wa lagbegbe Alakukọ lọna Dalemọ, niluu Eko,loun naa si bọ sita niwaju awọn eeyan to si n bura.

Muyideen Bello lo ti kọkọ sọ pe" Nigba ti ẹnikan to ti figba kan jẹ gomina nipinlẹ Ọyọ, Ajimọbi, isiaka Ajimọbi fẹẹ ṣe gomina, o pe mi, mo si sọ fun un pe ko jẹ ka pade nibi adura awọn alaafa kan

"O kọkọ beere lọwọ mi pe bi elo ni ki oun mu dani, mo si sọ fun un pe ọrọ eleyii ki i ṣowo, ko kọkọ wa sibẹ naa

"Niwaju awọn alaafa nigba naa ni mo ti sọ pe ko jade ko bura pe bi ko ba ni le tun ipinlẹ Ọyọ ṣe, ko ma debẹ amọ to ba jẹ pe yoo mu ilọsiwaju bawọn nibẹ, ki Ọlọrun gbe debẹ, adupẹ pe Ọlọrun gbadura ẹ lọjọ naa.

Iwọ Yayi, maa bọ nita bayii niwaju awọn alaafa lati bura pe to ba jẹ waa mu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun, ki Ọlọrun mu ẹ debẹ, amọ to ba jẹ idakeji ni, o o ni depo naa"

Niwọngba to si jẹ pe ere ti ọkunrin oloṣelu naa n sa kaakiri ni, kia o ti dide nibi to jokoo si lọ siwaju awọn aafaa.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe lakooko ti Yayi fẹẹ bura ṣe ni awọn ẹṣọ ẹ ni kawọn oniroyin atawọn to ya fidio pa kamẹra wọn, koda wọn ko mu lere o, to jẹ pe ṣe ni wọn n ṣọ awọn eeyan wọn ko si bikita lati ba foonu tabi kamẹra jẹ.

Lẹyin naa ni Sẹnetọ Yayi waa duro siwaju Muyideen Bello, to sọ pe "To ba jẹ pe lati mu idagbaoke ba ipinlẹ Ogun, ti ara yoo tu gbogbo araalu, ki Ọlọrun jẹ ki n wọle"

Bi o ṣe fẹẹ sọ idakeji ẹ ni aafaa to wa lẹgbẹ Muyideen Bello paa lẹnumọ, ti ko jẹ ko sọ ọ, lẹyin naa ni wọn ṣadura fun un.

Nbi ayẹyẹ ọhun ni Amin Ọlọrun tun ti fawọn eeyan kan ni awọọdu, lara wọn ni Shina Peller atawọn mii-ii.

Abdulkabir Ere Asalatu lo ṣere fun wọn lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages