Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, ọkan lara agba fẹgbẹ oṣelu PDP, lorileede yii ti sọ pe gbogbo agbara loun yoo sa lati rii pe ayipada rere ba ẹgbẹ naa lapapọ ti wọn ba foun laaye lati di alaga ẹgbẹ naa.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ nipa erongba ẹ lati di alaga ẹgbẹ naa lapapọ, eyi to ti wa lẹnu ẹ lati nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin.
O sọ pe iṣẹ akọkọ toun yoo ṣe ni lati jẹ ki ẹgbẹ ọhun waa nisọkan, ki wọn si yanju gbogbo awuyewuye to ti waa nilẹ,lẹyin naa loun yoo sa agbara lati rii pe agbara ijọba apapọ ati tipinlẹ pada bọ sọwọ PDP.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni akoko ti to fẹgbẹ naa lati ṣe atunṣe ati afomọ gbogbo awọn nnkan to n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ ọhun.
O sọ pe oun ti n gbe igbesẹ ati ifikunlukun pẹlu awọn agba ẹgbẹ ọhun eyi to si n fi oun lọkan balẹ pe didun ni ọsan yoo so boun depo naa nibi ipade gbogbogboo ti yoo waye ninu oṣu kẹjọ ọdun yii.
Ṣowumi tun ṣalaye pe oun ko nii jẹ ipin ipo sawọn ẹya to da wahala silẹ fun ti ipo aarẹ nibi ibo to kọja naa tun waye, nitori ẹ lawọn yoo ti ṣe awọn atunto ko to di pe ibo yoo waye.
O ni o yẹ kawọn agba ẹgbẹ naa fawọn ọdọ laaye lati lo ọpọlọ wọn, ki wọn fi dari, nitori ẹyin lo n di akukọ.
Nipa wahala to tun jẹyọ lori alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun ati Ọnarebu Ladi Adebutu, oludije gomina nibi ibo to kọla, Ṣowumi sọ pe ẹgbẹ ti kọja ibi teeyan ti le sun ko maa han oorun.
O sọ pe 'Ko si ọgbọn taa fẹẹ da, to ba jẹ pe awọn eeyan lo wa nibẹ,ayafi to ba jẹ awọn amunisin lo ku,wọn ki sii ṣe amunisin ẹgbẹ ni wọn, eyi ti wọn si n ṣe ko tii pọju,wọn gbaradi fun ipade gbogbogboo wọn ni"
O ni lagbara Ọlọrun yoo niyanju lẹyin ipade gbogbogboo ti wọn fẹẹ ṣe ati pe ki wọn ma ṣe gbagbe pe alaga ẹgbẹ ni Sikirulae Ogundele, agba ẹgbẹ si ni Adebutu,ipo wọn ko papọ.
Ṣowumi ni aṣẹ to wa lọwọ alaga ẹgbẹ si tun yatọ gedegbe si agba ẹgbẹ,amọ ṣa, awọn yoo fi igi ogolonto too, ti gbogbo ẹ yoo si yanju laipẹ.
Lori ọwọngogo epo bẹntiroolu to gbode, agba ẹgbẹ oṣelu naa sọ pe ọrọ naa ti wa n fẹ adura bayii nitori nnkan ti wọn n sọ ni pe bi wọn ba fowo kun owo epo yoo lọ silẹ, awọn eeyan yoo maa ri, amọ to jẹ pe bakan naa ni.
O sọ pe" Ẹni ti oye ba yee yoo mọ pe iromi to n jo, onilu kan wa nisalẹ omi to n lu ilu, ẹbẹ la maa bẹ awọn onilu ti wọn n lu,ki wọn jọ ọ ranti awọn mẹkunnu,ki wọn ma fọrọ epo fa kọngọ,ti yoo maa mu ifasẹyin ba ijọba''
Bẹẹ lo gba ijọba nimọran lati mojuto awọn nnkan to yẹ lati maa mojuto.
No comments:
Post a Comment