Ayeye isẹ̀dálẹ̀ ìtàn àti àjogúnbá ilẹ̀ Yorùbá lágbàáyé yóò wáyé nílùú Abẹ́òkúta. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 16 May 2024

Ayeye isẹ̀dálẹ̀ ìtàn àti àjogúnbá ilẹ̀ Yorùbá lágbàáyé yóò wáyé nílùú Abẹ́òkúta.


Gbogbo eto lo ti to fun ayẹyẹ iṣẹdalẹ itan ati ajogunba ilẹ Yoruba lagbaaye ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un, ọdun yii ni gbọngan aṣa ibilẹ Cultural Centre, niluu Abẹokuta.

Ọọni tilu Ile= Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi si ti ṣeleri pe oun yoo wa nibẹ lọjọ naa nitori ọkan lara ojuṣe to n jọba lee lori ni lati mu igbega ba oun gbogbo to ba jẹ ti iran Yoruba.

Bẹẹ lo tun sọ pe oun yoo sa gbogbo agbara oun lati jẹ ki gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba wa nibi ayẹyẹ to tun papọ mọ ayajọ ọjọ aṣa ti ajọ lagbaaye iyẹn United Nation fa kalẹ ni gbogbo ọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un lọdọọdun.

Lara awọn ti wọn tun reti lọjọ naa ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, aarẹ tẹlẹ lorileede yii, to tun jẹ Balogun Owu, awọn ọba alaye kaakiri ilẹ Yoruba,ẹgbẹ aṣa ibilẹ nilẹ Yoruba atawọn mii-ii.

Lakooko tawọn igbimọ to ṣeto ọhun ṣabẹwo lọọ sọdọ Ọọni, eyi ti Olori Ameenat Adelẹyẹ Matẹmilọla ṣaaju, lo tun ti fi atilẹyin ẹ han sayẹyẹ ọhun.

O sọ pe eto nla lawọn eeyan naa gbe da ni toun si gbọdọ fi atilẹyin ẹ han sii.O ni ọkan lara nnkan toun fi wa lori apere niyii, nitori o jẹ ọkan lara igbelarugẹ aṣa toun gbọdọ wa nijokoo lọjọ naa.

Ko to akoko yii ni Dokita Tọla Adenẹkan to jẹ alaga igbimọ, ti sọ pe eto yii jẹ eyi tawọn to mọ nipa aṣa ti wọn wa ni oke okun ṣonigbọwọ ẹ, lati fi ko gbogbo ọmọ Yoruba jọ fun ayẹyẹ itan iṣẹdalẹ ati ajogunba awọn ohun to jẹ ti iran Yoruba.

Lara awọn to tun sọrọ lọjọ naa ni Orunto tilu Owu, Oloye Ọladimeji Laṣile, toun naa jẹ ọmọ igbimọ lo ti sọ pe ayẹyẹ ọhun ni atilẹyin Olowu tiluu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla, ati pe pataki eto ọhun ni lati ma ṣe jẹ ki awọn ohun to jẹ mọ aṣa ko di oun igbagbe, bẹẹ lo ni ọdọọdun lawọn yoo maa ṣe e.

No comments:

Post a Comment

Pages