Ajadi Oguntoyinbo sayẹyẹ ọjọọbi iyawo ẹ lara ọtọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 9 May 2024

Ajadi Oguntoyinbo sayẹyẹ ọjọọbi iyawo ẹ lara ọtọ

Pẹlu orin iyin ati ọpẹ ni ọkan lara agba oṣelu, to tun jẹ oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP nipinlẹ Ogun, Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, fi ji iyawo ẹ, Oyindamọla, laarọ yii fun ti ayẹyẹ ọjọọbi obinrin naa to wayé lonii.

Se ni awọn eeyan ba wọn pe jọ ṣayẹyẹ ọhun nile ẹ, nibi ti gbogbo wọn ti jọ fimọsọkan gbe igba ọpẹ fun ti ayẹyẹ ọjọọbi naa.

Nigba to n ṣapejuwe oloolufẹ ẹ yii,o ni akọni obinrin to ti kopa to jọju ninu igbesi aye oun, eyi ti ko ṣee gbagbe.

Ajadi sọ pe" Oyindamla ki i ṣe iyawo lasan si mi, gẹgẹ bi ẹ mọ pe bo ba dara fun ọkunrin, obinrin ni. Gbogbo nnkan to le mu ifọkanbalẹ fun mi lo n ṣe, koda mi o kabamọ pe mo fẹẹ niyawo.

."Gbogbo atilẹyin lo n ṣe fun mi, eyi to jẹ ki aṣeyọri mi pọ si, gbọingbọin lo duro ti mi, mo waa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o fun mi ni aayo ọkan mi".

O waa gbadura fun un pe ki Ọlọrun lọra ẹmi ẹ fun un, ko ṣe ọpọ ọdun laaye.

No comments:

Post a Comment

Pages