Salvador gba ami ẹyẹ Ọjọgbọn nidii oṣelu nibi ayẹyẹ idanilẹkọọ Ramadan ọlọdọọdun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 24 March 2024

Salvador gba ami ẹyẹ Ọjọgbọn nidii oṣelu nibi ayẹyẹ idanilẹkọọ Ramadan ọlọdọọdun.




Ẹsẹ o gbero lọjọ Aiku, Sannde, nibi ayẹyẹ idanilẹkọọ ọlọdọọdun ti Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, maa n ṣe ẹlẹẹkẹdọgbọn iru ẹ, nibẹ ni wọn ti fi ami ẹyẹ Ọjọgbọn nidii oṣelu ati ọrẹ awọn mẹkunnu.

Ayẹyẹ ọhun to waye ni ọgba agba oloṣelu naa to wa ni Bọde Thomas, lawọn musulumi ọlọkan-ọ-jọkan ti peju pesẹ gẹgẹ bii ojuṣe wọn lọdọọdun.

Ninu ọrọ Ọgbẹni Johnson Akinpẹlu, ọkan lara awọn olootu iwe iroyin BOṢERI, ti wọn da Ọnarebu ọhun lọla, lo ti ṣapejuwe awọn ipa ribirbi ti Salvador, ti ko ninu agbo oṣelu ati bo tun ṣẹ lo awọn nnkan ini ẹ lati fi gbe awọn mẹkunnu

O sọ pe iru ọkunrin naa sọwọn lawujọ bẹẹ lo tun ni ọkan lara awọn olori ẹsin ti wọn karamasiki ni pẹlu.O ni gbogbo nnkan to ni lo fi n gbe ẹsin ga.

Ninu ọrọ Ọnarebu Salvador, nibi ayẹyẹ idanilẹkọọ Ramadan naa lo ti rọ gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ lati ṣe suuru pẹlu idaniloju pe nnkan pada bọ sipo rere.

Bẹẹ lo tun rọ wọn lati ma bawọn bu ijọba lakooko yii kaka bẹẹ adura lo ni ki wọn maa fi ran wọn lọwọ.

Salvador tun fikun ọrọ ẹ pe idanilẹkọọ ati fi fawọn eeyan ni nnkan ọdun lakooko naa ki i ṣe pe oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ati pe ọdọ baba to bi oun loun ti jogun ẹ.

O nigbagbọ oun ni pe beeyan ba ṣe ran awọn eeyan lọwọ lakooko awẹ yii bẹẹ ni ọna tiẹ naa yoo tubọ la si.

O le ni ẹgbẹrun meji awọn eeyan ti wọn kopa nibi eto tọdun yii, ti onikaluku wọn si rẹrin in lọ sile.




No comments:

Post a Comment

Pages