Lojumọ to mọ lonii, idagbasoke ti eto ẹkọ mu ba orileede ki i ṣe kekere, idi niyii to yẹ ki a fi maa karamasiki ẹ ni gbogbo igba, taa o si gbọdọ jẹ ko rẹyin.
Dokita Rafiu Adekọla Ṣoyẹle, ọga agba pata nileewe awọn olukọni ti apapọ iyẹn FCE, Oṣiẹlẹ, lo sọrọ yii nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn akẹkọọ wọn, ẹlẹẹdọgbọn, to waye ni ọgba ileewe ọhun lọsẹ to kọja.
O sọ pe ọrọ ẹgan kọ gbogbo awọn idagbasoke lawujọ lo jẹ pe imọ ẹkọ kun, idi niyii to si fi jẹ pe nileewe wọn to jẹ olukọni ṣe ni awọn ẹkọ mọkanlelọgbọn ti wọn n kọ awọn akẹkọọ wọn fun ti olukọni.
Bẹẹ ni ọga agba ọhun tun fi kun un ninu ọrọ ẹ pe ileewe ọhun tun ti n kọ awọn akẹkọọ lawọn ẹkọ to nii ṣe pẹlu awọn yunifssiti kan lorileede yii, ki wọn le gba imọ ijinlẹ digirii.
Dokita Ṣoyẹle waa mẹnuba awọn ipenija ti
wọn dojukọ lawọn ileewe olukọni, idi niyi ti wọn fi n tete pariwo ko ma ba di pe wọn wọgi lee lọjọ iwaju.
O waa fi akoko naa rọ ijọba apapọ lati gba ki ileewe olukọni maa ṣe digiri mọ iṣẹ wọn,nitori ki wọn maa baa palẹ awon ileewe naa mọ lọjọ iwaju.
Ninu ọrọ akọwe agba fawọn ileewe olukọni lorileede yii, Ọjọgbọn Paulinus Chijoke Okwelle, o gboriyin fun ileewe FCE, Oṣiẹlẹ lori bo ṣe n lewaju ninu awọn akẹgbẹ ẹ lorileede yii.
Bẹẹ lo tun mu da gbogbo awọn ileewe ọhun to wa lorileede yii loju pe ijọba Tinubu yoo tubọ maa ṣatilẹyin fun wọn, ki idagbasoke tun le maa deba awọn ẹkọ.
Lara awọn ti wọn fi ami ẹyẹ da a lọla niThe Olowu tiluu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla, Yeye Arẹmọ Temitọpe Adeọla, Dokita Chidiebere Gedeon Osi ati Dokita Ayọdele Adebayọ Ajayi.
No comments:
Post a Comment