Gẹnẹsis ṣeto ounjẹ fawọn musulumi lakooko awẹ Ramadan bẹẹ lo tun fẹẹ ṣe isin aṣalẹ atunṣe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 27 March 2024

Gẹnẹsis ṣeto ounjẹ fawọn musulumi lakooko awẹ Ramadan bẹẹ lo tun fẹẹ ṣe isin aṣalẹ atunṣe
Latigba ti awẹ awọn musulumi ta a mọ si Ramadan ti bẹrẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Isreal Ọladele Ogundipẹ tọpọ mọ si Genesis, ti bẹrẹ ṣiṣe eto ounjẹ fawọn musulumi to gbawẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igba akọkọ kọ ree ti yoo maa ṣeto iru nnkan bẹẹ lakooko ti awẹ ba n lọ lọwọ.

Eyi si jẹ ara iranlọwọ to n ṣe fawọn to ku diẹ kaato lati mu inu wọn dun.

Bakan naaGbogbo eto lo ti to lati ileeṣẹ iranṣẹ Genesis Global city, fun isin aṣalẹ atunṣe iyẹn Restoration night,ti yoo waye lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu yii ninu ijọ naa.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ lati gbọ pe aago mẹjọ alẹ ni eto ọhun yoo bẹrẹ nibi tawọn olorin ẹmi ọlọkan-ọ-jọkan yoo ti pitu ọwọ wọn.

Lara wọn ni Dare Oxygen, Moji Genesis, Solomon Mayọwa atawọn mii-ii bẹẹ ni Wolii Isreal Ogundipẹ tọpọ mọ si Genesis yoo tun rọjo adura le awọn eeyan lori lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages