O sọrọ yii lakooko ti wọn ṣebura fun oun atawọn oloye ẹgbẹ ọhun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, eyi to waye lonii ni ọfiisi INEC, to wa ni Magbọn, niluu Abẹokuta.
O sọ pe ki wọn ma ṣe maa foju alatako wo awọn ẹgbẹ oṣelu ti ko si nijọba kaka bẹẹ ki wọn faye gba ifikunlukun ati bi ajọṣepọ to danmọran yoo ṣe wa, ni eyi ti yoo mu iṣejọba rere waye.
Abayọmi tun fikun ninu ọrọ ẹ pe akoko ti to lati jẹ ki alaafia jọba laarin awọn oloṣelu nipinlẹ Ogun.
O sọ pe " A fẹẹ ki ijọba ipinlẹ ati gbogbo ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun fun ẹgbẹ IPAC, ni ọwọ to ba tọ sii nitori a kii ṣiṣẹ fun alatako ati pe a kii ṣe alatako rara. Gbogbo waa la jọ ni, wọn ko si le loo lati fa eeyan kalẹ.''
O ni tijọba ba ṣe daadaa dandan ki awọn gboriyin fun, to ba si ku diẹ kaato, a gbọdọ pariwo wọn sita.
Ninu ọrọ Ọgbẹni Niyi Ijalaye, to jẹ ọga agba fajọ INEC, nipinlẹ Ogun, ẹni ti Thomas Ọlawuyi, o ki awọn oloye ẹgbẹ tuntun naa ku oriire,bẹẹ lo tun fi akoko naa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu yii fun ti ibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2027.
No comments:
Post a Comment