Ẹ jẹ ka fi akoko ọdun ajinde yii fi ifẹ so ara wa pọ-Alaga fẹgbẹ IPAC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 31 March 2024

Ẹ jẹ ka fi akoko ọdun ajinde yii fi ifẹ so ara wa pọ-Alaga fẹgbẹ IPACAlaga fegbe apapọ awọn oloṣelu nipinlẹ Ogun, Abayọmi Sanyaolu, ti rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati lo akoko ọdun ajinde to wa lode yii fun ẹmi ifẹ iṣọkan laarin awọn mutumuwa.

Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade to fi sita lati fi ki gbogbo awọn ọmọ lẹyin Kristi fun ti ayẹyẹ ọdun naa to n lọ lọwọ. Pẹlu adura pe ki Ọlọrun fi ayọ ati idunnu to wa ninu ajinde kun ọkan onikaluku.

Bẹẹ lo tun gba awọn eeyan lamọran lati lo anfaani to wa ninu ọdun ajinde lati fi gba ifẹ ati iṣọkan laaye gẹgẹ bi ẹbi kan, ki a ma fi ti oṣelu, ẹlẹyamẹya tabi ẹsin ṣe.

Bakan naa lo tun bawọn ọmọ ẹgbẹ IPAC naa ṣajọyọ ọdun tuntun, to si tun gboriyin fun wọn fawọn ipa ti wọn ti ko fun idagbasoke ẹgbẹ naa latẹyin wa.

O waa ṣadura pe ki Ọlọrun ko ṣamọna, ko si dari wọn fun ọjọ iwaju lati le jẹ ki erongba wọn so eṣo rere, ki ẹmi agbọye le jọba laarin wọn.

Abayọmi tun wa rọ awọn eeyan lati nawọ ọdun ajinde ọhun de ọdọ awọn alabaagbe, awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ lati dide iranlọwọ si wọn.

Bẹẹ lo tun fi adura ran ipinlẹ Ogun naa lọwọ pẹlu amọran pe ki ifẹ ko jọba.

No comments:

Post a Comment

Pages