Lati ọsẹ to kọja ni nnkan ko tii danmọran laarin ijọba ipinlẹ Ogun ati ẹgbẹ awọn oṣere nipinlẹ naa, nitori bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ aṣa ati irinajo afẹ nipinlẹ naa ṣe paṣe pe wọn yoo maa gba ẹgbẹrun lọna ogun naira lọwọ wọn ni gbogbo igba ti wọn ti wa fun igbaradi ere wọn, ti wọn n ṣe ni abẹ igi, ninu ọgba gbọngan naa, to wa niluu Abẹokuta.
Ọgbẹni Bahir Sanni, to jẹ gomina fẹgbẹ awọn oṣere ANTP nipinlẹ Ogun, lo kọkọ fi aidunnu wọn han lori igbesẹ naa, ko to waa di pe ẹgbẹ oṣere ọmọbibi ipinlẹ naa fi ẹhonu wọn sita.
Ninu atẹjade ti Ọnarebu Kẹhinde Ṣoaga, to jẹ akọwe gbogbogboo ẹgbẹ naa ati Ọgbẹni Bayọ Bankọle, tọpọ mọ si Boy Alinco, toun jẹ ọmọ igbimọ fi sita, ni wọn ti tako igbesẹ ọhun patapata, ti wọn si beeere lọwọ ijọba to wa lode naa pe kin ni atilẹyin ti wọn ti ṣe fawọn lati nnkan bi ọdun mẹrin abọ, ti wọn ti n ṣejọba bọ.
Wọn ẹgbẹrun lọna ogun Naira ti wọn fẹẹ maa gba lọwọ awọn oṣere ti wọn n lo abẹ igi fi se igbaradi ko bojumu rara, ti gbogbo ẹgbẹ oṣere ko si le tẹwọgba.Wọn ni lẹyin pe wọn fowo tun gbọngan aṣa ibilẹ naa ṣe, ki i si ṣe nitori awọn oṣere bi ko ṣe nitori ipade oṣelu tabi ti wọn ba fẹẹ ṣe nnkan laarin ara wọn.
Ẹgbẹ naa wa rọ Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun,lati tete dide si ọrọ naa, ki o gbe awọn igbesẹ to ba yẹ, ko si wo gbogbo ipenija tawọn oṣere ọhun ni pẹlu ọna abayọ.
No comments:
Post a Comment