Olu itori fẹbun tọrẹ fawọn ọmọ ti ko niya l’ Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 28 February 2024

Olu itori fẹbun tọrẹ fawọn ọmọ ti ko niya l’ AbẹokutaFun ayẹyẹ ayajọ ogun ọdun, to ti de gba ade, gẹgẹ bi Olu- Itori, to n lọ lọwọ,  Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ, ti lọọ fẹbun tawọn ọmọ ti ko niya lọrẹ, lati le mu inu wọn dun.

Nibi ayẹyẹ ọhun to waye nibẹ ni Ọnarebu Motunrayọ Adija Adelẹyẹ, to jẹ kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ogun, ti ki ọba naa kaabọ sile awọn ọmọ alainiya  Stella Ọbasanjọ, to wa ni Ibara, niluu Abẹokuta.

Bẹẹ ni kọmiṣanna fẹmi imoore ẹ han si nnkan ti ọba alaye naa ṣe pẹlu awọn ẹbun olowo nla ti wọn fi wa awọn ọmọ naa lọrẹ. Bakan naa lo tun rọ awọn ọba alade yooku atawọn ẹlẹyinju anu lati fi iru nnkan bẹẹ ṣe awokọṣe rere.

Lẹyin ti wọn kuro nibẹ, ni wọn tun gba ileewe Mercy Land, to wa ninu Ibara ọhun lọ nibi ti wọn ti ṣayẹyẹ nla fun Olu-Itori nitori awọn ipa ribiribi to ti ko sileewe naa, Ninu ọrọ ti Ọba Abdulfatai Akamọ, lo ti sọ pe oun fi ayẹyẹ ogun ọdun ọhun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ipa to ti ko latigba toun ti di ọba ilu Itori.

No comments:

Post a Comment

Pages