Mo ṣetan lati tẹsiwaju ninu aanu ti mo n ṣe fawọn mẹkunnu-Ajadi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 2 January 2024

Mo ṣetan lati tẹsiwaju ninu aanu ti mo n ṣe fawọn mẹkunnu-Ajadi



Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, ti sọ pe oun yoo tubọ maa tẹsiwaju ṣiṣe awọn mẹkunnu laanu, nitori ọkan pataki to jẹ oun lọkunkun dun, ti oun ko nii fa sẹyin.

Ọkunrin yii sọrọ naa lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ayẹyẹ ọdun tuntun to ṣe, eyi to waye lagbeegbe Torotoro, Ọrẹmeji, niluu Ibafo, nipinlẹ Ogun.

O sọ pe awọn nnkan ribiribi toun ṣe lati mu igbe aye ọmọniyan dun lo jẹ ki wọn maa fi ami ẹyẹ da oun lola, eyi to jẹ ohun iwuri foun lati maa tẹsiwaju, nitori oun mọ pe ere pọ nibẹ.

Ajadi to ti figba kan dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP,  to tun gba ami ẹyẹ oriṣiriṣi nibi ayẹyẹ ọdun naa, lara ẹ ni Ọrẹ Awọn Mẹkunnu ti ileeṣẹ iwe iroyin BO ṢE RI fi daa lọla tun ṣalaye pe oun nigbagbọ pe didun ni ọsan yoo so ninu ọdun yii.

O sọ pe ọpọ awọn akanṣe iṣẹ lo wa niwaju oun toun fẹẹ ṣe fun irọrun awọn ọmọ ọrileede yii bẹẹ lo ni oun ko ni kaarẹ rara lori ẹ.

Nibi ayẹyẹ ọdun ọhun lawon olorin ọlọkan-ọjọ-kan ti forin da awọn eeyan lara ya, lara wọn ni Alaaji Abass Obesere, nigba ti Baba Labule ṣaaju awon to dari eto.

No comments:

Post a Comment

Pages