Ambasedọ Yẹmi Farounbi, ọkan lara awọn igbimọ alamojuto fẹgbẹ oṣere tiata ANTP lorileede yii ti bẹbẹ fun ayipada rere fẹgbẹ ọhun, ki awọn ogo ẹ le pada bọ sipo.
Ilu Ibadan lo ti sọrọ ọhun nibi alẹ apejẹ ti wọn ṣe fawọn oloye ẹgbẹ tuntun, eyi to jẹ akọkọ iru ẹ latigba ti wọn ti da ẹgbẹ naa silẹ.
Nibi eto naa lawọn agba oṣere bii Oloye Lere Paimọ, tọpọ mọ si Ẹda Onileọla, Alagba Yẹmi Ẹlẹbuibọn, Alagba Oyewọle Olowomojuọrẹ Baba Gebu,Oloyẹ Ọlọrunọjẹ ati Alagba Eletu.
Ambasedọ Farounbi ṣalaye siwaju pe ẹgbẹ oṣere ANTP, ti kọja eyi ti wọn le maa foju abuku wo nita gbangba nitori awọn ipa to ti ko sẹyin lati ọdun 1977,ti wọn gba iwe ẹri pe wọn da a silẹ.
Bẹẹ lo mẹnuba ipa tawọn agba oṣere bii Oloye Hubert Ogunde, Mosses Ọlaiya, Akin Ogungbe, Kọla Ogunmọla atawọn mii-ii ti ko ninu ẹgbẹ naa ko to di pe wọn jade laye.
O waa sọ pe akoko ti to bayii lati bẹrẹ si ni lo ẹbun ti Ọlọrun fun wọn nidii iṣẹ tiata ati pe wọn yoo bẹfẹ si nii ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan laipẹ.
Ninu ọrọ Oloye Lere Paimọ, lo ti rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lati gba ifẹ laaye ninu ẹgbẹ naa, ki wọn si sọ ara wọn di ọkan.
Alagba Olowomojuọrẹ lo da wọn lẹkọọ nipa bi ilọsiwaju yoo ṣe deba iṣẹ tiata.Aarẹ ẹgbẹ naa, Rasak Ọyadiran dupẹ lọwọ gbogbo awọn igbimọ agba ẹgbẹ naa fun ayẹyẹ ọhun, eyi toun naa jẹri sii pe ko tii waye ri.
O waa ṣeleri pe igba ọtun ti bẹrẹ si nii debe ANTP lati akoko yii lọ.
No comments:
Post a Comment