Ojurere ati aanu Ọlọrun lawọn eeyan nilo lakooko yii-Wolii Genesis - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 18 December 2023

Ojurere ati aanu Ọlọrun lawọn eeyan nilo lakooko yii-Wolii Genesis




Wolii Isreal Ọladele, tọpọ awọn eeyan mọ si Genesis, ti rọ awọn ọmọ orileede yii lati maa wa ojurere ati aanu lati ọdọ Ọlọrun wa, nitori nnkan ti wọn nilo lakooko yii niyẹn.

Ọjiṣẹ Ọlọrun sọrọ yii nibi ayẹyẹ ajọdun ọlọdọọdun to maa n ṣe, eyi ti irufẹ ẹ waye lana- an, Sunday, ninu ijọ ẹ to wa ni Alakukọ, nipinlẹ Eko.

O sọ pe ojurere ati aanu lati oke wa lo le mu awọn eeyan kuro ninu oko inira, ki wọn di ominira, ki ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ, ko le tẹ wọn lọrun.

Bakan naa lo tun gba awọn ọmọ orileede yii lamọran lati ma ṣe dakẹ nipa fifi adura ran awọn aṣaaju wa lọwọ, ki wọn le ṣe nnkan to tọ ati eyi to yẹ fawọn to wa labẹ wọn.

Wolii Genesis tun fikun ọrọ ẹ pe ko si nnkan ti eeyan ba n ṣe laye yii, ti ko ba si ojurere Ọlọrun nibẹ, otubantẹ lo pee.

O wa ni gbogbo igba tawọn eeyan ba ti n gbadura, ohun akọkọ ki wọn maa beere ni ki Ọlọrun ran Angẹli to ni ojurere sọdọ wọn.

Nibi ajọdun lawọn olori ijọ atawọn ọmọ ijọ sẹlẹ ti waa bawọn sajọyọ bẹẹ lawọn olorin ẹmi naa ko gbẹyin. Pabanbari ẹ ni tawọn akanda eeyan ti wọn waa forin da wọn laraya.

No comments:

Post a Comment

Pages