Ikunlẹ abiamọ o! Ọrẹ meji pa ọmọleewe OAU, nitori oogun owo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 9 December 2023

Ikunlẹ abiamọ o! Ọrẹ meji pa ọmọleewe OAU, nitori oogun owo


Pẹlu bawọn alaabo ilu ṣe n fojoojumọ gbogun tawọn ti wọn n wa ọla ojiji, ti wọn fi ọmọnikeji wọn ṣoogun owo lawujọ sibẹ awọn kan ko jawọ, iṣẹ naa ni wọn si mu lọkunkundun ti ẹmi ọmọnikeji wọn ko jọ wọn loju

 

Lara awọn ni ọrẹ meji kan, Akeem Usman ati Ifadowo Niyi, tọwọ palaba wọn ṣẹgi lọsẹ to kọja, nigba ti wọn pa Quadri Salami, ọmọleewe giga yunifasiti Ọbafẹmi Awolọwọ.

 

Ninu iwadii wa la ti gbọ pe ṣe ni awọn afurasi mejeeji ọhun da ẹmi ọmọleewe naa, to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun legbodo, ti wọn pa nipakupa bẹẹ ni wọn yọ lara ẹya ara ẹ, ti wọn si lọ sin iyooku ara ẹ.

 

Ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta, ni agbẹnusọ wọn, Ọmọlọla Odutọla, ti kọkọ kede nipa iṣẹlẹ ọhun lakooko ti wọn mu awọn afurasi yii.

 

O sọ pe baba ọmọ ti wọn pa yii lo waa fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa to wa ni Kemta, lọjọ kẹrinla, oṣu to kọja pe oun ko ri ọmọ oun yii, o ni lọjọ kẹjọ, oṣu naa lawọn ti rii gbẹyin.

 

Iwadii tawọn ọlọpaa ṣe lọ jẹ ki wọn mu Akeem Usman, ti wọn ri foonu Quadri lọwọ ẹ. Ohun lo si jẹ ki aṣiiri tu, to si mu awọn ọlọpaa lọ si agbegbe kan ti wọn pe ni Mile 6, ni Ajebọ, niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti sin ẹya ara Quadri.

 

Akeem yii lo wa jẹwọ pe oun ati Ifadowo Niyi, lawọn jọ ṣiṣẹ naa, tawọn jọ ẹya ara ọmọleewe naa fun oogun owo. O sọ pe ori ati ọwọ ẹ lawọn ta ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira.

 

O ni inu akaunti owo  oun ni wọn san owo naa si gẹgẹ bawọn ṣe ṣadehun ẹ fun ẹni to fẹẹ ra ati pe ẹya ara yooku lawọn lọọ sin ni ọganjọ oru.

 

Ni bayii, awọn ọlọpaa ti n tẹ siwaju ninu iwadii wọn lori iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ ni wọn sọ pe ọwọ yoo tẹ ẹni ti wọn ta a fun laipẹ ati pe awọn meji ọhun yoo foju bale ẹjọ

 


No comments:

Post a Comment

Pages