Aṣofin Ọlamilekan Adeọla, to n ṣoju ẹkun Ogum West, nile igbimọ aṣòfim agbs niluu Abuja, ti rọ gbogbo awọn ẹlẹsin kristi, lati lo akoko ọdun keresi yii jẹ ki igbagbọ wọn duro ninu Jesu Kristi,lati fi gbadura igbe aye ọtun lorileede yii.
O sọrọ naa ninu iṣẹ to ran lati bawọn kristẹẹni ṣajọyọ ọdum tuntun, eyi ti Oloye Kayọde Ọdunaro fi sita lorukọ aṣofin naa.
O ṣalaye ṣiwaju pe adura ni orileede wa nilo lakooko yii lati fi ran ijọba to wa lode yii lọwọ.
Aṣofin tun fikun ninu iṣẹ ọdun to ran naa pe ohun ti ọdun keresi naa duro lori ajọyọ ibi olugbala fun igbala ẹmi paapaa julọ awọn ẹlẹsin igbagbọ.
O nitori idi eyi la ṣe gbọdọ lo akoko naa lati wa ireti fun ọjọ iwaju wa.
Aṣofin Adeọla tun sọ pe, " Mo rọ gbogbo ẹyin onigbagbọ orileede yii lati lo ọdun keresi, ti ọdun 2023, lati fi tubọ sunmọ Ọlọrun, ki wọn si gba alaafia, ifẹ ati iṣọkan laaye lorileede yii ki ijọba to wa lode yii le ṣaṣeyọri"
O ni loootọ lawọn ọmọ orileede yii n koju ipenija nipa ọrọ aje, ti gbogbo nnkan ko jọ ara wọn. Amọ ṣa, oun gbawọn niyanju lati ṣe suuru, ki wọn si foriti pẹlu igbgbọ pe yoo pada bọ si rere laipẹ.
No comments:
Post a Comment