Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ajọ kan to n jẹ ọkọ opo lati pa awọn opo to le ni ọgọrun-un lẹrin nipa fi fun wọn ni ẹbun lọjọ keji ọdun keresi.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọjọ naa ni Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ, to jẹ onigbọwọ eto ọhun yoo fawọn opo ni ẹbun ounjẹ ati owo bẹẹ ni wọn tun ti pese mọto silẹ ti yoo gbe awọn eeyan ọhun lọ sibi ti eto yii yoo ti waye, iyẹn Pelican Valley, Laderin niluu Abẹokuta.
Ohun ti wọn sọ pe ajọ ọkọ opo naa waa fun ni lati maa dide iranwọ fawọn to ba ku diẹ kaato fun yala ọmọde tabi agbalagba lati maa mu inu wọn dun lawujọ.
Eto ọhun ni wọn sọ pe yoo bẹrẹ ni aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹdogun pẹlu awọn adari eto bii agba ọjẹ nidii iṣẹ iroyin Eddy Aina, Tọpẹ Adaramọla, Ernest Nwokolo, to jẹ aṣoju kọ iroyin fun iieeṣẹ iwe iroyin.
Bakan naa ni awọn igbimọ alaṣẹ Pelican ti aṣoju wọn Alagba James Sẹinde, tọpọ mọ Pa James.
Adeyẹmọ tun fikun ọrọ ẹ pe awọn adari eto naa ni yoo tun lo akoko yii lati fi tan
imọlẹ erongba ajọ ọhun fawọn araalu.
Bẹẹ lo sọ pe lẹyin naa ni wọn yoo ṣe ipade pọ pẹlu awọn opo to le ni ọgọrun-un, nibi ti ilanilọyẹ yoo tun ti waye.
Bakan naa ni Alaaja Sidikat Adeyẹmọ, to
jẹ Iya Adinni Ginti,musulumi,Ikorodu yoo ti bawọn eeyan sọrọ nipa iriri ẹ gẹgẹ bi opo.
Nigba to n sọ idi pataki to fi da ajọ naa silẹ,Ọmọwe Adeyẹmọ sọ pe oun ti ba Ọlọrun da majẹmu pe oun yoo fi gbogbo ara ati ọkan oun silẹ lati maa ṣetọju awọn opo lati jẹ ki wọn mọ pe ireti wa.
O tun sọ pe oun ko fẹẹ ko dabi oṣelu tabi ki wọn ki i bọ, nitori bawọn ba ṣe e bẹẹ awọn yoo bara awọn nidii ẹ, oun ko si fẹ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment